NAFDAC: Ohun tí wọ́n fi ń se báàgì, bàtà ni wọ́n ń tà bíi ‘pọ̀ǹmọ́

NAFDAC Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Àjọ NAFDAC ti ní àwọn ọlọ́jà káràkátà kan ń lo awọ ẹran màálù tí wọ́n fi ń ṣe báàgì tàbí bátà látì fi ṣe pọ̀nmọ́.

Ajọ to n mojuto ọrọ ounjẹ ati oogun lorilẹede Naijiria, NAFDAC ti tẹnu mọọ fun awọn ọmọ Naijiria lati sọra fun pọnmọ jijẹ.

NAFDAC, ninu atẹjade lati ọwọ adari ẹka naa, Arabinrin Mojisola Adeyeye fi lede, wi pe awọn eniyan n lo awọ ẹran maalu ti awọn ile-isẹ to n ṣe baata tabi baagi ra lati fi se pọnmọ ti awọn eniyan n jẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionN100,000 Nairà mà ni Dino gbé dání lójú agbo, kò náwó yàlà-yòlò - Ayefele

Adeyeye ni ọpọ igba, wọn o ti lo ‘chemical’ si ara awọn awọ ẹran maalu naa fun lilo, ko to di wi pe awọn eniyan ma a wa loo fun pọnmọ jijẹ.

Bakan naa ni NAFDAC fi kun wi pe, awọn miran tun n gbe awọ maalu wọle si Naijiria lati orilẹede Turkey ati Lebanon ni ọna ti ko ba ofin mu. Eleyii ko si ni fun wọn laaye lati woo finifini.

Ajọ naa wa parọwa si awọn ọmọ Naijiria lati sọra fun pọnmọ jijẹ, ki o ma ba a fa aisan aimọdi si ara awọn eniyan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKayeefi: Facebook ni Wolii Arole Jesu fi tàn an wọ agbo, orí rẹ̀ ni wọ́n fi s'owó