Oluwo of Iwo: Nàìjíríà, sọ́ra, ogun ń sọ ilé ọlá di ahoro!

Oluwo Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Oluwo ti ilu Iwo, Oba Abdulrasheed Akanbi ti kìlọ̀ fún ìjọba láti dojú kọ ètò ààbò tó mẹ́hẹ kí ogun ó má báa wáyé.

Oluwo ti ilu Iwo, Oba Abdulrasheed Akanbi ti kọ lẹta si Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari, fun igba akọkọ lori ipaniyan awọn Fulani darandaran ni orilẹede Naijiria.

Ninu lẹta naa, Oba Abdulrasheed Akanbi sọ wi pe oun kii kọ lẹta ni gbogbo igba, amọ lati dawọ ipaniyan duro ati ki ogun ma ba a sẹlẹ ni Naijiria ni oun fi kọ lẹta naa si Aarẹ Buhari.

Oluwo ti ilu Iwo ni ija ati asọ kọ ni ọna abayọ si eto aabo to mẹhẹ, amọ ki ijọba fi agbara fun ẹkọ ati iwe kika, eleyii ti o le mu ki awọn eniyan ni ọgbọn ati imọ wi pe ogun kọni ọna abayọ si ipenija to n koju araalu ni Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionN100,000 Nairà mà ni Dino gbé dání lójú agbo, kò náwó yàlà-yòlò - Ayefele

Bakan naa ni Ọba Akanbi wa rọ Aarẹ Buhari lati ba awọn adari ni gbogbo ẹkun lati sọra fun ọrọ ẹnu wọn, ki alaafia ba le jọba lorilẹede Naijiria.