Ruga Settlement: Ganduje ní káwọn Fulani darandaran kúrò lápá gúúsù Nàìjíríà

Gaa Fulani Image copyright Getty Images

Gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje ti woye pe tawọn Fulani darandaran ko ba kuro lapa Guusu Naijiria, ọrọ ruga ko le lojutu.

Gomina Ganduje ṣalaye pe ni wọn igba tawọn Fulani ẹlẹran ọsin ba n dẹran lati apa ariwa Naijiria lọ si aarin gbungbun ati guusu, ọrọ ruga ati isọro eto aabo to mẹhẹ ko le dopin.

O fikun ọrọ pe ko yẹ, ko lẹtọọ ki ruga wa lawọn ipinlẹ tawọn Fulani darandaran ti jẹ alejo.

Ganduje ijọba apapọ kọ lo yẹ ko ṣagbatẹru ọrọ ruga fawọn Fulani ẹlẹran ọsin, o ni awọn ipinlẹ to ba nifẹ sii lo yẹ ko ṣagbatẹru eto naa.

Gomina Ganduje fikun ọrọ pe ipinlẹ Kano ti ya ibi kan sọtọ fawọn Fulani lati maa fi ẹran jẹko.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Bakan naa, o sọ pe aikawe ọpọn ninu wọn lo ṣokunfa ki ọpọ wọn ti di agbebọn bayii.

Ganduje koro oju si bi awọn Fulani ti n ṣi kiri lati apa ariwa Naijiria lọ si apa aarin gbungbun ati Guusu Naijiria.

Bakan naa, o sọ pe aikawe ọpọ ninu wọn lo ṣokunfa ki ọpọ wọn ti di agbebọn bayii.

Ganduje ni ipese ruga lo le dẹkun iṣoro tawọn Fulani n koju, o ni ti wọn ba loju kan ni wọn fi le jẹgbadun awọn ohun ameyedẹrun bi awọn ara ilu yoku.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNigeria Pensioners: Wàhálà àyẹ̀wò iwé ìfẹyinti yì ti pọ̀jù