Presidency: Aarẹ Buhari kẹdun ikú àwọn eniyan to kagbako Boko Haram

Buhari Image copyright @Presidnecy
Àkọlé àwòrán Ironu dori agba kodo

Aarẹ Mohammadu Buhari bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu ikọlu awọn alakatakiti ẹsin Islam, Boko Haram ni Borno

Mallam Garba Shehu to jẹ olubadamọran fun aarẹ Buhari lori ọrọ iroyin ati ifitonileti gbogbo sọ ninu atẹjade kan to fi sita pé nkan ibanujẹ lo ṣẹlẹ yii.

O ni awọn ọmọ ogun ilẹ ti fi da aarẹ Buhari loju pe awọn oniṣẹ ibi boko Haram to ṣiṣẹ yii a jẹ iyan wọn ni iṣu laipẹ.

Garba Shehu ni ijọba apapọ n gbe gbogbo igbesẹ to yẹ lati daabo bo ẹmi ati dukia awọn eniyan Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionShiite: Ẹ̀mí àti ara wa kọ ohun tí ìjọba ń ṣe sìwa láti 2015

Ileeṣẹ aarẹ ni ijọba ko ni kọ ohun ti yoo na oun lati sọ ọrọ awón agbesunmọmi di ohun igabgbe ni Naijiria.

Garba Shehu ni lọwọlọwọ ni awọn ọmọ ogun ilẹ̀ ati ti ofurufu ti bẹrẹ igbesẹ lati ṣawari awọn oniṣẹ ibi yii pẹlu aṣẹ aarẹ Buhari.

Bakan naa lo fi da awọn eniyan Maiduguri ati awọn aṣatipo loju pe ijọba ti fi kun eto aabo ẹkun yii lati dena iru iṣẹlẹ bayii.

Ìkọlù àwọn ti Boko Haram pa níbi ìsìnkú Borno ti lé síi

Odiwọn iye awọn to ba ikọlu Boko haram to ṣẹlẹ yii lọ ti di marun dinlaadọrin bayii.

burnt Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Iṣẹlẹ yi waye nipinlẹ Borno lọsẹ ti o pe ọdun mẹwaa ti Boko Haram bẹrẹ si ni ṣoro ni Naijiria.

Ileeṣẹ amohunmaworan agbegbe Maiduguri ṣalaye pe bi wọn ṣe n pada bọ lati ibi isinku ni wọn ti kagbako awọn alakatakiti ẹsin Islam, Boko Haram.

Wọn kólu wọn ni abule Badu-Abattari to wa ni bii ọgọfa kilomita si Maiduguri to jẹ olu ilu ipinlẹ Borno.

Mohammed Bulama to jẹ alaga ijọba ibilẹ naa ni awọn eniyan mọkanlelogun ni wọn kọkọ pa ki wọn to tun wa lọ kọlu awọn ara abule to n gbeja awọn ero.

oku Image copyright @Audu
Àkọlé àwòrán ikú to n pa ojugba ẹni ni ọrọ yii n di ni Naijiria

Ọkan ninu awọn ọgagun ẹkun yii to ni ki BBC ma darukọ oun ṣalaye pe lojiji ni oun kọkọ gba ipe pajawiri lori iṣẹlẹ naa.

Ni eyi ti wọn ni eniyan mẹtalelogun ti gbẹmi mi lati Nganzai ni eyi ti awọn eniyan Badu Kuluwa si wa ninu ipaya.

Bẹẹ, o ti pẹ ti awọn agbesunmọmi alakatakiti ẹsin Islam boko haram ti n da ẹmi awọn eniyan legbodo.

Iroyin ti a ti ri gba tẹlẹ:

Boko Haram ṣíná fún àwọn tó lọ ìsìnkú, èèyàn 23 pàdánù ẹ̀mí wọn.

Iṣẹlẹ yi waye nipinlẹ Borno lọsẹ ti o pe ọdun mẹwaa ti Boko Haram bẹrẹ si ni ṣoro ni Naijiria.

Awọ̀n ọmọ ikọ Boko Haram Image copyright BBC/Boko Haram
Àkọlé àwòrán Awọn Adunkoko mọni Boko Haram sefilọlẹ idunkuuku laja wọn lọdun 2009

Awọn eeyan mẹtalelogun to n dari bọ lati ibi isinku kan nipinlẹ Borno ti ko agbako iku lọwọ ikọ agbesunmọmi Boko Haram.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹwa lọwọ, iṣẹlẹ naa waye lagbegbe Nganzai ni nnkan bi ago mọkanla owurọ ọjọ Abamẹta.

Ọkan lara awọn asaaju agbegbe ti iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ, Bunu Bukar Mustapha ti o ba awọn ile iṣẹ iroyin AFP sọrọ ṣalaye pe lati abule Badu Kuluwu lẹba Goni Abachari ni awọn eeyan naa ti n dari bọ nibi ti wọn ti lọ sin oku kan.

Bunu ni ''oku eeyan mẹtalelogun lawọn eeyan wa gbe kuro nibi iṣẹlẹ naa lowurọ oni''

Awọn alaṣẹ ko ti i fi idi ọrọ yi mulẹ fun BBC titi di igba ti a fi ṣe akojọpọ iroyin yi.

Àwọn ìròyìn míì tí ẹ tún le nífẹ́ sí:

Lọsẹ́ to kọja yi ni o pe ọdun mẹwaa ti Naijiria bẹrẹ si ni koju ipenija awọn alakatakiti ẹsin Islam, Boko Haram ti ọpọ ẹmi ati dukia si ti ba a lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIbadan Accident: Èèyàn méjì kú, ẹnìkan wà nílé ìwòsàn