Ọlọ́pàá ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti sanwó ìtaràn £2500 fún oníwàásù ọmọ Nàìjíríà tí wọn mú lọnà àìtọ́

Paito Oluwole Ilesanmi Image copyright Christian Concern
Àkọlé àwòrán Paitọ Oluwole Ilesanmi yoo fi iwe ẹhonu sọwọ si ileeṣẹ ijọba eleyi ti awọn eeyan fọwọsi lati le daabo bo awọn to n ṣe iwaasu nita gbangba

Oniwaasu Kristẹni kan ni awọn ọlọpaa ilẹ Gẹẹsi ko panpẹ si lọwọ ti wọn si fipa gba bibeli lọwọ rẹ.

Lẹyin iṣẹlẹ yii lo wa di ẹni ti awọn ọlọpaa yoo san owo gba ma binu ẹgbaa le ẹdẹgbẹta pọun fun un.

Fọnran fidio ibi ti oniwaasu Oluwole Ilesanmi ti n bẹ awọn ọlọpaa ki wọn ma ṣe gba bibeli rẹ lawọn eeyan ti wo ni igba miliọnu mẹta le loju opo ayelujara.

Iwaju ibudoko ọkọ oju irin Southgate ni wọn ti da a duro losu keji ọdun yi lẹyin ti ipe kan wole pe o n sọ ọrọ to korira ẹsin Islam.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDaddy Freeze s'alaye n to faa ti oun fi n tako idamẹwa

Ile iṣẹ ọlọpaa ilẹ Gẹẹsi ni ẹtọ awọn ni lati ṣe iwadii ọrọ tawọn fura si pe o nii ṣe pẹlu idunkooko mọ awọn eeyan ẹya kan tabi ẹlẹsin miran.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLeke Adeboye: Àwọn aláwáda tó fẹ́ irànlọ́wọ́ iléèwé

Ninu fọnran fidio naa ni ọgbẹni Ilesanmi to jẹ ọmọ ọdun mẹrinlelọgọta ti n sọ fun awọn ọlọpaa naa pe ''Jesu nikan ni ọna iye''

Ọlọpaa to mu u ninu fidio naa si n sọ pe ''Mi o ba ọ jiyan amọ ko si ẹni to fẹ gbọ ohun to n sọ. Wọn fẹ ki o kuro nibi ni' "

Image copyright Christian Concern
Àkọlé àwòrán Ninu fọnran fidio to gbode Paitọ Ilesanmi n bẹ awọn ọlọpaa lati ma ṣe gba bibeli rẹ

Nigba ti ọgbẹni Ilesanmi fẹ mu bibeli rẹ, ọlọpaa naa sọ fun un pe ''o ba ti ro o daadaa ki o to bẹrẹ si ni sọ ọrọ abuku nipa ẹlẹsin miran''

Ọgbẹni Ilesanmi ni lootọ lohun sapejuwe ẹsin Islam gẹgẹ bi ohun ti ko bojumu amọ ero ọkan tohun ni gẹgẹ bi Kristẹni kii ṣe pe ohun bẹnu atẹ lu awọn musulumi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionShiite: Ẹ̀mí àti ara wa kọ ohun tí ìjọba ń ṣe sìwa láti 2015

Lọjọ Iṣẹgun, ọgbẹni Ilesanmi yoo fi iwe ẹhonu sọwọ si ileeṣẹ ijọba eleyi ti awọn eeyan fọwọsi lati le daabo bo awọn to n ṣe iwaasu nita gbangba.

Bi ọlọpaa ṣe mu mi da ibẹrubojo simi lọkan

Ileeṣẹ ọlọpaa ti gba pe awọn yoo san owo gba ma binu ẹgbaa le ẹdẹgbẹta poun fun un tori bi wọn ti ṣe fipa gba bibeli rẹ ti wọn si doju ti .

Ọgbẹni Ilesanmi ni ''Inu mi dun pe ọlọpaa mọ pe awọ́n ko lẹtọ lati mumi tori pe mo n fi bibeli ṣe iwaasu.''

O tẹsiwaju pe ''Iṣẹlẹ naa jami laya nigba ti wọn mu mi, ṣugbọn ko ko irẹwẹsi ọkan bami lati pada lọ Southgate lọ ma ṣe iwaasu nitagbangba.''