Emirate Cup: Lyon figbájú olóòyì méjì gba Emirate Cup lọ́wọ́ Arsenal

Agbabọọlu Arsenal Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹpa o boro mọ fun Arsenal

Ẹkun ohun oṣe ni Arsenal fi pari ifẹsẹwọnsẹ oloresọrẹ wọn ninu idije Emirate Cup ti wọn fi sọri wọn.

Ẹgbẹ agbabọọlu Lyon ti ilu Faranse lo ṣe iya fun Arsenal, ti wọn si gbe ife Emirate Cup naa mọ Arsenal lara niwaju awọn alatilẹyin Gunners.

Moussa Dembele, atamatase ti Lyon gbe wọlẹ ni o da bira pẹlu goolu meji ni abala ikeji idije naa.

Pierre Emerick Aubameyang ti saaju gba bọọlu sawọn fun Arsenal ni abala ikini ṣugbọn eleyi ko ja mọ nkankan nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa yoo fi wa si opin.

Ni bayi, ireti Arsenal lati fi ife ẹyẹ yi bẹrẹ saa bọọlu tuntun yi ti ja si asan ti awọn alatilẹyin ẹgbẹ naa kan si ti n faraya loju opo Twitter.

Àwọn ìròyìn míì tí ẹ tún le nífẹ́ sí: