Àwọn ọmọ Nàìjíríà kan fẹ́ kí ilé ẹjọ́ ó fagilé orúkọ Buhari gẹ́gẹ́ bi olùdíje APC

Ontẹ ile ẹjọ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn ọmọ Nàìjíríà kan fẹ́ kí ilé ẹjọ́ ó fagilé orúkọ Buhari gẹ́gẹ́ bi olùdíje APC

Awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria mẹta kan ti pe ẹjọ tako Aarẹ Muhammadu Buhari nile ẹjọ to gaju ni Naijiria.

Wọn ni pe ko ni iwe ẹri to daju lati fi du ipo aarẹ ninu eto idibo ọdun 2019.

Awọn olupẹjọ, Kalu Kalu, Labaran Ismail ati Hassy Kyari El-Keris tọ ile ẹjọ lọ pe ko fagile Buhari gẹgẹ bi oludije nitori iwe ẹri ileewe to lọ.

Awọn olupẹjọ sọ pe Buhari parọ ninu ibura to kọ silẹ ninu iwe to fun ajọ eleto idibo INEC lasiko to fi erongba rẹ lati dupo han.

Ṣaaju ni ile ẹjọ giga ijọba apapọ nilu Abuja, ati ile ẹjọ kotẹmilọrun ti da ẹjọ wọn nu ninu idajọ kan lọjọ kejila, oṣu Keje, ọdun 2019.

Ile ẹjọ ni pe oun ko le gbọ ẹjọ naa nitori pe o ti le ni ọjọ mẹrinla ti ofin la kalẹ lẹyin ti Buhari gbe igbesẹ naa ki wọn o to o gbe ẹjọ wa sile ẹjọ.

Eyi lo mu ki wọn o gbe ẹjọ lọ siwaju ile ẹjọ to gaju pe ko fagile idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun, ko si gbọ ẹjọ naa lọtun.

Lara awọn nkan ti wọn n fẹ ki ile ẹjọ o ṣe ni pe ko dajọ pe Buhari ko sọ otitọ fun ajọ INEC nipa iwe ẹri ileewe to lọ.

Bakan naa ni wọn fẹ ki ile ẹjọ o paṣẹ fun ajọ INEC lati yọ orukọ Buhari kuro gẹgẹ bi oludije ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC.