Lagos Building Collapse: Ilé alájà méjì wó lu ọmọ mẹ́rin ni Bariga

Àkọlé àwòrán Ile ọhun da wo lasiko ti atunṣe fẹ bẹrẹ

Ilé to wa ni ojule ọgbọn ni adugbo Ọsọsa ni Bariga ni ipinlẹ Eko lo wo ti awọn ọmọ mẹrin si farapa ninu ẹ.

Akọroyin BBC to wa nibẹ n ṣalalye nsiyi pe, onile naa ti bẹrẹ igbeṣẹ lati tun ile naa ṣe ki o too da wo lulẹ.

Okan lara awọn ayalegbe to n gbe nile naa, ọgbẹni Kabiru ni opo ile naa kan lo kọkọ da wo ni ijẹta ni eyi ti onile fẹ tun ṣe.

Àkọlé àwòrán Ibeji ati Idowu wọn di ero ilé iwosan ni Bariga

Ogbẹni Kabiru ni oun ti fẹ ko kuro ninu ile naa tẹlẹ nitori pe ojoojumọ ni ibi kọọkan n ya ti iho n han nibẹ ti ile naa si n sọ òkò ifura.

Bawo lo ṣe ṣẹlẹ?

Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko, LASEMA ni nkan bii aago mẹsan an abọ alẹ ana (ọjọ Aiku) ni awọn gba ìpè sori aago wọn lori iṣẹlẹ naa.

Nọmba ti LASEMA fi sita lati maa pe fun ifitonileti iṣẹlẹ pajawiri ni 767 / 112.

LASEMA ni kete ti wọn de ibi iṣẹlẹ naa ni wọn rii pe ile alaja meji ọhun lo ti wo de ilaji to si wo lu awọn ọmọ mẹrin ninu rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸni to ni ile iwe sare lati doola awọn akẹkọ ni ile wolu

Ibeji obinrin ati Idowu wọn ọkunrin lo wa ninu ilé alaja meji naa ati ọmọkunrin miran ni eyi ti wọn ti ko wọn lọ sile iwosan lẹyin ifarapa wọn.

Àkọlé àwòrán ọpọ ile lo ti di ẹgẹrẹmiti ni ipinlẹ Eko ti ijọba si ti fẹ ṣe ayẹwo lori wọn

Iṣẹ iwadii ti wọn ṣe lori ile to wo naa fihan pe ile naa ti la ni awọn ibi kan tẹlẹ ni eyi ti ọgbẹni Ayilara to nii ko tete ṣatunṣe to yẹ si.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOnimọ nipa ile kikọ sọwipe ijọba nilo awọn onimọ nipa owo ori ile

Wọn ti ko awọn ti wọn farapa lọ si ile iwosan ijọba ni Gbagada nipinlẹ Eko.

Àkọlé àwòrán Number ti LASEMA fi sita lati maa pe fun ifitonileti iṣẹlẹ pajawiri ni 767 / 112.

Awọn oṣiṣẹ eleto aabo ti di ọna si ile alaja meji na pa ki o ma lọ wo tan lu awọn eniyan lẹyin ti wọn ko gbogbo ayalegbe kuro.

Àkọlé àwòrán ọpọ ile lo ti di ẹgẹrẹmiti ni ipinlẹ Eko ti ijọba si ti fẹ ṣe ayẹwo lori wọn

Omọwe Olufẹmi Oke- Osanyintolu to jẹ adari agba ajọ LASEMA ti parọwa fun baba onile naa lati jẹ ki ajọ LABSCA to n yẹ ile wo nipinlẹ Eko ṣiṣẹ wọn bi o ti yẹ.

Àkọlé àwòrán Lagos Building Collapse: Ilé alájà méjì wó lu ọmọ mẹ́rin ni Bariga

Ọpọlọpọ ile ni awọn ijọba ti ya sọtọ lati wo ni ipinlẹ Eko bayii.

Àkọlé àwòrán LASEMA n ke gbajare lori awọn ile ti o ti daagun

Igba akọkọ kọ ni yii ti ile a da wo nipinlẹ Eko, koda, ọkan ṣẹlẹ loṣu kéfa ọdun 2019 ni adugbo Mafoluku lasiko ti wọn n tun un ṣe lọwọ.