Shiite: Ilé ẹjọ́ gíga Kaduna sún ìgbẹ́jọ́ adarí Shiite síwájú

Adari ẹgbẹ Shiite, El-Zakzaky

Ijoko ile ẹjọ giga ni Kaduna ko waye lonii lori gbigbọ ẹjọ lati gba oniduro adari ẹgbẹ Shiite, El-Zakzakky.

Nibayii ọjọ karun un, oṣu kẹjọ ni igbẹjọ naa yoo waye nitori El-Zakzakky funrarẹ ati iyawo rẹ ko fara han nile ẹjọ bi o tilẹ jẹ wi pe agbẹjọro wọn, Femi Falana sọ eredi pe tori ailera ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionShiite: Ẹ̀mí àti ara wa kọ ohun tí ìjọba ń ṣe sìwa láti 2015

Ọrọ aabo ti peleke sii ni olu ilu ipinlẹ naa ṣaaju igbẹjọ naa ninu eyi to si ti mu ẹmi ọlọpaa kan ati akọroyin lọ.

Lori ẹsun mẹjọ ọtọọtọ ni adari ẹgbẹ Shiite El-Zakzaky ati iyawo rẹ, Zeenat fi n koju ile ẹjọ eyi ti ijọba ipinlẹ Kaduna fi kan wọn.

Awọn ẹsun naa ni i ṣe pẹlu pipaniyan lọna aitọ, ipejọpọ ti ko bofin mu ati dida omi alaafia ilu ru ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Lati inu ọdun 2015 ni wọn ti fi El-Zakzaky satimọle.

Awọn Iroyin mii ti ẹ le nifẹ si