Ministerial Screening: Aregbesola, Fashola àti Gbemi Saraki wí tẹnu wọn

Rauf Aregbesola
Àkọlé àwòrán Rauf Aregbesola

Gomina ana nipinlẹ Osun Ọgbẹni Rauf arẹgbẹsola ni inu oun dun pe ẹni to gba ipo lẹyin oun ṣi n san gbese ti oun jẹ kalẹ.

Lasiko ayẹwo to waye niwaju ile aṣofin agba fawọn ti aarẹ Buhari yan sipo Minisita ni o ti lede ọrọ yi ni ọjọ Aje.

Nibi ayẹwo Minisita niwaju ile asofin Naijiria naa ohun ati awọn miiran bii Babatunde Fashola ati Gbemisola Saraki yọju siwaju ile lati wi tẹnu wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn oṣiṣẹ feyinti ni Osun ṣé iwọde

Rauf Arẹgbẹsọla ti o jẹ Gomina ipinlẹ Osun nigba kan ri ni wọn bo ti ṣe koju ipenija airi owo oṣu awọn oṣiṣẹ san ti o si fi gbese kalẹ nigba ti yoo fi kuro lori alefa.

Awọn aṣofin bii meji kan beere ọrọ yii ti o si dahun pe ''awọn to n sọrọ nipa owo osu nipinlẹ Osun lasiko toun wa lori alefa kan n wi eleyi ti o wu wọn ni.'

Aregbesola ni ijọba oun na owo pupo lori pipese oun amayederun lo faa ti sisan owo oṣu fi mẹhẹ fawọn oṣisẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionShiite: Ẹ̀mí àti ara wa kọ ohun tí ìjọba ń ṣe sìwa láti 2015

Lẹyin atotonu awọn aṣofin si gba Aregbesola laaye ki o tẹriba niwaju ile ko si maa lọ.

Iru aaye tẹriba ko maa lọ yi naa ni awọn aṣofin fi gba Gbemi Saraki to jẹ minisisita lati ipinlẹ Kwara.

Saraki to ti jẹ Ṣẹneto tẹlẹ ri to si tun jẹ obinrin ko tilẹ dahun ibeere kankan ti ile fi gba a laaye lati maa lọ.