Tá láwọn ọba aládé àti olóṣèlú tí EFCC n wà lórí owó ìrànwọ́ N2bn ní Kwara?

Eniyan to nka owo Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn olokoowo alabọde lo yẹ ki wọn pin owo yi fun ṣugbọn EFCC ni idameji owo naa bọsi owo awọn oloṣelu ati ọba alade kan

Omi ti tẹyin wọ igbin lẹnu nipinlẹ Kwara nibi ti ọwọ ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra EFCC ti tẹ oludari ile ise to n risi awọn olowo alabọde nibẹ,Segun Soewu lori ẹsun ajẹbanu.

Biliọnu meji naira ni ajọ naa ni oludari yi ati awọn miran lu ni ponpo.

Loju opo EFCC lori Facebook ni wọn fi iroyin yi si ninu atẹjade kan.

Gẹgẹ bi atẹjade naa ti ṣe sọ, oludari ileeṣẹ naa ko tẹle ilana to yẹ nipa pipin owo to yẹ ki wọn fun awọn oniṣowo kaakiri ijọba ibilẹ mẹẹdogun ipinlẹ Kwara.

EFCC sọ pe Soewu to wa ni ahamọ lọdọ awọn pin owo naa fawọn oloṣelu ati awọn Ọba alade kan.

Koda ọba alade kan gba miliọnu méjídínlọ́gọ́rin naira ninu owo naa ti ko si da pada,

EFCC ni ''oba alade yi gba owo iranwọ naa lorukọ ileeṣẹ rẹ Yafy International Ventures Limited ti ko si tẹlẹ ilana to yẹ''

Ẹwẹ EFCC tun darukọ awọn oludari ileifowopamọ kan pe wọn mọ nipa apapin owo yi.

Titi di bi a ti ṣe n ko iroyin yi jọ.EFCC ko darukọ ọba alade ti o bawọn pin ninu owo yi amọ ajọ naa ninu ọrọ oju opo wọn ni oludari ileeṣẹ to n risi awọn owo alabọde tawọn mu ti n wi tẹnu rẹ lọdọ awọn.