Lagos- Ibadan Express: Kò sí ìfòyà lásìkò ọdún iléyá

Àkọlé àwòrán Kò sí ìfòyà lásìkò ọdún iléyá ní òpópónà Marosẹ Eko si Ibadan

Ìjọba àpapọ̀ ti fi ọkàn àwọn ará ìlú balẹ̀ pàápàá jùlọ àwọn to ń lo ọ̀pópónà márosẹ Lagos -Ibadan wi pé àwọn yóò fi ààyè silẹ̀ fún ìrìnnà ọkọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.

Wọn ni ayẹyẹ ọdún iléya tó ń bọ̀ àti ti ìpàdé àpapọ ìjọ RCCG tí yóò wáyé ní àṣẹ́ ṣe lọ pé kí kọngila tó ń siṣẹ́ ọ̀nà náà dẹwọ́ gbogbo àwọn ojú pópó ti wọ́n dí.

Ìgbésẹ̀ yìí kò ṣeyin bí àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣe bẹnu ẹ̀tẹ́ lu ìpínnú àwọn kọngila láti dí àpá ibikan pa fún iṣẹ́ àkanse lóju pópó náà bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ kẹta, oṣù kẹjọ ọdun.

Alákoso iṣẹ́ àti ìrìnnà ní ìpínlẹ̀ Eko, ọgbẹ́ni Adedamola Kuti sàlàyé pé pẹ̀lú ìwòye àwọn lóri bí ìgbòkègbodò ọkọ̀ yóò ṣe pọ̀ tó, ó di dandan kí ẹdínkù bá ìṣẹ́ tí wọ́n yóò ṣe ni àsìkò náà.

Adedamola Kúti ní bí i kìlómítà kan ó lé ọwọ́ mẹ́rin tí wọ́n fẹ ṣe àtúnse rẹ̀ láti Berger si afára Kara bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Satide.