Naomi Adamu se àkọsílẹ̀ ìgbé ayé rẹ̀ ni àgọ́ Boko Haram

Image copyright AFP/BOKO HARAM
Àkọlé àwòrán Mo ní ìwé àkọsílẹ̀ ìgbé ayé mi ni àgọ́ Boko Haram- Naomi Adamu

Ó pé ọdún mẹ́wàá gbáko tí ọ̀gá àwọn alakatakiti ẹsin Islam Boko Haram ti gbogbo ènìyàn mọ̀ si Mohammed Yusuf kú

Yusuf kú nígbà ti ó wà ní àhámọ́ ọlọ́pàá ní ìlú Maiduguri, sùgbọ̀n láti ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹ́ ní omi àláfíà ìhà árèwá Nàìjíríà àti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lápapọ ti dàrú.

Ọ̀pọ̀ òjò ti rọ̀ ti ilẹ̀ si ti fi mu, ọ̀pọ̀ ẹ̀mi dúkìá àti ilé ló ti bá àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí o wáyé lẹ́yìn náà lọ.

Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ní ìjínígbe àwọn ọmọ ilé ìwé tí ilé ìwé Chibok sì jẹ ọ̀kan lára wọn ti ero n sọrọ lori rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIya Adura Esther Ajayi sọ àṣírí owó rẹ̀ tó fi ń ṣàánú

BBC ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ̀núwò fún Naomi Adamu tó jẹ́ ọkan nínú àwọn ọmọ Chibok tí Boko Haram jígbé ní ọdún 2014 tó si lo ọdún mẹ́ta gbáko ni àhámọ wọn.

Naomi sàlàyé pé nínú àhámọ Boko Haram, wọ́n pin ìwé kíkà fún àwọn láti máa fi kọ ẹkọ́ ìmọ̀ Kuran.

Ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ yìí ń fi àwọn ìwé náà ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ǹkan ti ó ń sẹlẹ̀ àti àṣírí tó ń tú sí wọn lọ́wọ́ nínú àhámọ́ Boko Haram.

Nígbà ti àwọn Boko Haram ri ǹkan ti àwọn ọmọ náà ń ṣe, wọn gbà á, wọ́n sì dáná sún awọn iwe naa.

Sùgbọ́n ní ti Naomi àti olólùfẹ́ rẹ̀ tí wọ́n maa ń wà papọ, Sarah Samuel tó jẹ ẹni ogún ọdún gbìyànjú láti fi ìwé tiwọn pamọ àti ìwé àwọn ọmọbinrin mẹ́ta míràn tí wọ́n máa ń kọ àwọn ìrírí wọ́n sí.

Àkọlé àwòrán Ìwé àkọsílẹ̀ tí Naomi pamọ lásìkò tó wà ní àhámọ Boko Haram nínú ìgbó Sambisa

Èdè Oyinbo àti Hausa ní wọ́n fi kọ ìwé àkọsílẹ̀ wọn yìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí àkọsílẹ̀ àwọn ọjọ ìṣẹ̀lẹ̀ sùgbọ́n ó dàbí ẹni pé àkọsílẹ̀ náà wáyé ni oṣù àkọ́kọ́ tí wọ́n wọ àhámọ Boko Haram

Nkan mẹ́wàá (10) tí wọ́n ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀

1. Kìí ṣe àwọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ ni Boko Haram fẹ́ jí gbé

Ìjínigbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Chibok tó wáye ní ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù kẹrin, ọdún 2014 kìí ṣe láti ji àwọn ọmọbinrin Chibok gbe bíkò ṣe láti jí ẹ̀rọ tí wọ́n fí ń mọ búlọkù, ìṣẹ́ ilé kíkọ to ń lọ witiwiti nínú ọgbà ilé ẹkọ́ náà ní bi ọsẹ̀ díẹ̀ sí ìgbà náà.

Nínú ìwé ti Naomi kọ, ó sàlàyé pé lẹ̀yìn gbọnmisi-omi-o-tó láàrin wọn ni wọ́n pa ọkan pọ láti ji àwọn akẹ́kọ̀ọ́, ó fi kún un pé lẹ́yìn ti àwọn dé ibẹ̀ wọ́n kò mọ ǹkan ti wọ́n ó fiwọ́n ṣe kóda wọ́n gbèrò láti sun wọ́n níná ni nibẹrẹ.

2. Ìtàn nípa bí wọ́n ṣe fẹ́ sá kúrò

Bí wọ́n ṣe ju ọ̀pọ̀ sínú ọkọ ti wọ́n gbé wá ní wọn ni ki àwọn kan máa fí ọwọ́ kọ́ àra wọn lọ́rùn.

Kí wọ́n maa rin pọ̀ pẹ̀lú ìbọ́n lẹ́yìn wọ́n ti wọ́n si fi ẹsẹ̀ rín ibi tó jìnnà.

Àkọsílẹ̀ yìí jẹ́ ti Naomi Adam àti Sarah Samuel, Rhoda Peter, Sarah Job àti Margaret ti wọn jẹ mẹ́rin nínú awọ́n tí orí kọ́ yọ̀ nínú oṣù karun un, ọdún 2017.

Sarah Samuel gbà láti fẹ́ ọ̀kan nínú wan ó sì kọ̀ láti pada wále

Àkọlé àwòrán Iwe àkọsílẹ̀ Naomi ní èyí nibi tí ó kọ gbogbo ìrírí rẹ̀ sí

Nígbà ti wọ́n fẹ́ sálọ, ọkan nínú wọ́n ké gbàjare sí àwọn Boko Haram ní wọ́n fí wọ́n mú u pada.

3. Gbogbo Ọgbọ́n àlùmọ̀kúrọ́yin wọ́n

Oníruurú àwọn ọgbọ́n tí wọ́n maa n lo lati fi dẹ́rùba àwọn ọmọ tó wà ni àhámọ ní pe wọn tí gbé ọpọ ninu àwọn obi wọn náà.

Ìgbà míràn ẹ̀wẹ̀, wọ́n a gbé gálọọnù jáde bi pé èpo ló wà nínú rẹ̀, wọ́n a wá sọ fún wa pé tí ako ba gba Islam àwọn ó dáná sún wa, ìdí nìyí ti àwọ́n míràn fi gba ẹ̀sìn.

4. Ìnú ń bí Boko Haram pé wọ́n ń fi ẹsùn ìfípabánilò kàn wọ́n

Àwọn ọmọbinrin ti wọ́n fi ọ̀rọ̀ wá lẹ̀nu wò, sàlàyé pé wọ́n ó fi ipá bá àwọn lò tàbí fẹ́ àwọn ni túlàsì, sùgbọ́n nígbà míràn wọn máa n ba àwọn sọ ọ̀rọ ìgbéyàwó

Àkọlé àwòrán àwọn ọmọbinrin náà fi ìwé náà pamọ

Nínú àkọsilẹ̀ wọ́n, wọn ni Boko Haram ń binu lori ìròyin pé àwọn ń fipa ba àwọn náà lajọṣepọ̀,

Bakan naa ni wọn máà ń wa wàásù sí àwọn ni alaalẹ́ ki awọn le kọ nipa Jihad ati ẹsin Islam sii.

5. O gbọdọ̀ wọ́ Hijab kí ẹmi okunkun ma ba a dé bá ọ

Àkọlé àwòrán Mo ní ìwé àkọsílẹ̀ ìgbé ayé mi ni àgọ́ Boko Haram- Naomi Adamu

Wọ́n fún àwọn náà ni Hijab nítori wọ́n kò fẹ́ máá ri àra wọ́n, bákan náà ni wọ́n máa n ka kurani fún wọ́n nigbogbo igba.

6. Wọ́n máa n bawa sọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó.

Ni àsìkò ti wọ́n ba ti ba wa sọ̀rọ̀ ìgbéyàwó wọn a fún wa ni àsìkò láti ronu sii sùgbọ́n wọn kìí fẹ́ ẹni ti kò ba gba Islam.

O gbọdọ gba Islam ni akata Boko Haram ki wọn to le fẹ ọ ni iyawo.

Ẹrú si ni irú ẹni ti ko ba gba Islam jẹ fún àwọn to ba gbà láti fẹ́ àwọn Boko Haram.

Naomi sàlàye pé ẹni ti kò ba ti fẹ wọ́n yóò fọsọ, pọnmi, yóò si maa bọ̀wọ̀ fún ìyàwó wọ́n

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán ipolongo "Bring back our girls"

7. Àwọn ará ìlú ń da àwọn to bọ́yọ lọ́wọ́ Boko Haram padà si àgọ́ wọ́n

Pẹ̀lú bí gbogbo àyé ṣe gbe ìfẹhonu han lóri ìjínigbé àwọn ọmọ Chibok síbẹ̀ àwọn kan o bikítà ti wọ́n sì ń dá àwọn tí wọ́n sá kúrò ni àhámọ Boko Haram pada si bẹ̀.

Kò si ounjẹ gidi tàbi omí, kò sí ilé.

Ní ọ̀pọ̀ ìgbà tí a ba sá kúrò ni àhámọ ti àwọn ará ìlú sì gbọ́ pé ahamọ Boko Haram ni a ti wa, wọ́n fà wá le wọ́n lọ́wọ́ pada, nítori wọn ò fẹ́ ni ǹkan ṣe pẹ̀lú wọn.

8. Wọ́n ń fipa múwa láti dí Musulumi

Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọn máa ń sọ fún wa pé tí a ba ti gbà láti di Musulumi ní àwọn yóò dá wa padà sí ọ̀dọ̀ àwọn òbí wa.

Wọn maa n sọ pe ki a ṣe musulumi dandan nitori pe ẹni tó ba ti kọ̀ lati di musulumi kò ni kúro lọ́dò àwọn.

Ati pe awọn ko ni tu ẹni ti wọn ka si keferi ti ko tii gba Islam silẹ.

Image copyright AFP/BOKO HARAM
Àkọlé àwòrán Mo ní ìwé àkọsílẹ̀ ìgbé ayé mi ni àgọ́ Boko Haram- Naomi Adamu

9. Wọ́n fẹ́ràn láti máa fí fọ́nran síta

Àwọn Boko Haram maá ń sáabà sẹ fídíò nígbà míran kété ti wọ́n ba ti wo ìròyìn tán.

Wọ́n a bẹ̀rẹ̀ si ni pe wa ní ẹyọ kọọkan láti sọ orukọ wa, wọ́n a fẹ ki a jẹ ki ìjọba àti àwọn obi wá mọ pe àwọn ò fi ìyà jẹ wá.

Ati pe a ṣi wa laye ni ahamọ wọn

10. Awọn Boko Haram maa ń wo ìròyìn púpọ̀

Àwọn Boko haram maa ń gbọ iroyin gbogbo nkan to n ṣẹlẹ ni agbaye.

Eyi to ba kan wọn lo maa n jẹ ki wọn gbe ọ̀pọ̀ fídíò sita fi tako iroyin nipa wọn ní kété ti wọ́n ba ti wo ìròyìn tán.

Ní ọjọ kan bí wọ́n se wo ìròyìn BBC Hausa tán ní wọ́n ba pè wá ni ọkọ̀ọkan àwọn míràn kúnlẹ̀ nígbà ti àwọn kan dúró, wọ́n ni ki a maa ka kùrán sita.

Kíní ó sẹ̀lẹ̀ sí àkọwé yìí

Naomi àti àwọn mẹ́ta tó ku tó fi mọ Rhoda Peter, Sarah Job àti Magaret Yama ní wọ́n tú sílẹ̀ ní inu oṣù Karun un, ọdún 2017

Ìjọba si rán wọn lọ fásitì Yola nínú oṣù kẹsan an, ọdun 2017

Naomi sàlàyé pé òun kọ àkọsílẹ̀ nítori pé òun fẹ ki ọmọ àti àwọn òbi oun ríí.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionShiite: Ẹ̀mí àti ara wa kọ ohun tí ìjọba ń ṣe sìwa láti 2015