Boko Haram: igba marun un ti Shekau ku ti ko tun ku mọ

Abubakar Shekau Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Boko Haram: igba marun un ti Shekau ku ti ko tun ku mọ

Boko Haram ko deede ṣẹlẹ ni Naijiria.

Lọdun 2002 ni Mohammed Yusuf da Boko Haram silẹ lati tako ẹkọ nilana oloyinbo nibi ti aye laju si loni.

Bẹẹ, ọpọ igbesẹ lo maa n bẹrẹ pẹlu erongba rere ṣugbọn ti igbẹyin rẹ le ma dara bii ti Boko Haram to ti di igi ose ti ipa ko fẹ ka mọ.

Yusuf lo pilẹ ẹgbẹ naa amọ lẹyin iku rẹ lọwọ awọn ọlọpaa lọdun 2009 ni Abubakar Shekau kede ara rẹ lẹyin ọdun meji iku Yusuf gẹgẹ bi olori Boko Haram.

Kete ti awọn alakatakiti ẹsin Islam Boko Haram kede orilẹ-ede ara wọn ni ero awọn eniyan nipa wọn yipada.

Ariwo Shekau ku ti ko tun ku mọ to tun jinde ti waye ni ọpọ igba kaakiri Naijiria.

Titi di bi a ṣe n sọrọ yii, ko si ẹni to le fọwọ sọya boya o ku tabi ko ku.

Ta ni Abubakar Shekau ti Boko Haram?

Omo ipinlẹ Yobe ni ariwa ila oorun Naijiria ni Abubakar Shekau jẹ.

Omo iran Kanuri ati Elẹsin musulumi ni Abubakar.

Oun ni igbakeji ẹgbẹ Boko Haram ti Mohammed Yusuf da silẹ lati tako imọ nipa iwe kika lọna igbalode.

O di olori awọn agbesunmọmi Boko Haram lẹyin iku ọga rẹ lati ọwọ awọn agbofinro lọdun 2009.

Opọ ẹmi ati dukia lo ti ba iwa ipa ati igbesunmọmi awọn Boko Haram rin ni Naijiria ni eyi ti ọpọ si ti di alarinkiri ati aṣatipo lagbaye.

Wo àwọn ìgbá ti Abubakar Shekau ti ku ni Naijiria:

Ọpọlọpọ igba ni wọn ti kede pe ijọba Naijiria ti rẹyin Abubakar Shekau lati ọdun 2009 ti Naijiria ti n ja ogun ikọlu awọn alakatakiti ẹsin Islam naa.

Igba akọkọ

Igba akọkọ ti wọn kede iku Shekau ni lọdun 2009.

Nigba ti awọn ọmọ ogun Naijira dawọpọ kọlu ikọ agbesunmọmi Boko Haram.

Lẹyin ti wọn pa eniyan to le ni ọgọrun un lasiko naa ni awọn kan tun ni irọ nipe Shekau ku lara wọn.

Ko pẹ lẹyin ikede oku rẹ yii lo tun sọrọ jade ninu fidio kan lori ayelujara to fi tun kede ara rẹ gẹgẹ bii ọga agba pata fun awọn Boko Haram.

Igba ikeji ti Shekau di oloogbe:

Lọdun 2013 ni awọn ọmọ ogun ilẹ Naijiria tun kede pe awọn ti ṣe Abubakar Shekau leṣe lasiko ti wọn kọlu Boko Haram ni ariwa Naijiria.

Wọn ni ninu igbo Sambisa ni awọn ti kọlu Shekau ti wọn si ti ṣee lọṣẹ to kọja bẹẹ.

Nigba ti o di oṣu kẹsan an ọdun naa lẹyin ti ọpọ ti fi idunnu han pe wọn rẹyin odì ni fidio kan ba tun jade ti Shekau ti ni laaye ni oun ṣi wa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionShiite: Ẹ̀mí àti ara wa kọ ohun tí ìjọba ń ṣe sìwa láti 2015

Igba Ikẹta lẹyin iku Shekau:

Lọdun 2014 ni iroyin tun jade pe awọn ọmọ ogun ilẹ Naijira ti gbẹmi olori awọn oniṣẹ ibi Boko Haram.

Wọn ni ninu igbo Kodunga lawọn ti paa nigba ti awọn ọmọ ogun Naijiria gbena woju awọn agbesunmmi naa.

Ojo kejila, oṣu kẹsan an si ọjọ kẹrinla, oṣu ni wọn fi jọ n ja ijajangbara naa.

Awọn ọmọ ogun ilẹ Cameroon naa sọ pe ootọ ni iṣẹlẹ yii.

Koda wọn ko awọn aworan kan sita to ṣafihan oku Shekau.

Ko pẹ lẹyin eyi ni Shekau gbe fidio miran sita to fi yẹyẹ awọn ọmọ ogun orilẹ-ede mejeeji pe oun kú tì!

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Mo ku ti ni ọrọ Shekau

Igba ikẹrin ti wọn ṣofọ Abubakar:

Lọdun 2015 ni aarẹ orilẹ-ede Chad, Idriss Deby sọ pe o ti tan fawọn alakatakiti ẹsin Islam Boko Haram.

O sọ eyi nigba ti ọrọ Boko Haram ti n gbẹbọ lọwọ Orilẹ-ede Naijiria, Chad, Niger ati Cameroon.

Idriss ni olori miran ti gbaṣẹ lọwọ Shekau nitori opin ti de baa.

Ara ọtọ ni Abubakar fi sọ pe oun ṣi wa laye lọtẹ yii nipa lilo fonaran olohun fi sọrọ pe oun ni oun ṣi n dari Boko Haram o.

O ni laiku ẹgiri, ẹnikan kii fawọ rẹ ran gbẹdu ni ọrọ oun o.

Igba karun un ti Shekau ku lọwọ ijọba:

Awọn ọmọ ogun ofurufu Naijiria lo ṣe ikede ti ọtẹ yii.

Lọdun 2016 ni wọn ni ọfa ikọlu wọn ti ba Abubakar nibi to lapẹrẹ ati pe oku ni ẹlẹja n taa lo maa pari ikọlu ọhun.

Won ni koda awọn pa awọn olori boko Haram miran sii labule Taye.

Wọn ni eyi ṣẹlẹ lasiko ti wọn sọ ado oloro lati oju ofurufu lọjọ kọkansinlogun, oṣu kẹsan an ọdun 2016.

Ni Shekau naa ba gba ori You tube ayelujara lọ lati ṣe afihan fidio pe lakọ ni oun wa.

Boko Haram Bayii:

Iroyin to n lọ lasiko yii ni pe awọn Boko Haram ti pin si ẹya meji pẹlu olori ọtọọtọ.

O ti le ni ọdun mẹwaa ti wọn ti n ṣọṣẹ ni ariwa ila oorun Naijiria atawọn orilẹ-ede miran.

Wọn ni awọn ẹya kan ti lọ darapọ mọ Islamic State of West Africa Province.

Diẹ lara iṣẹ ijinigbe ti wọn ti se ni jiji awọn ọmọbinrin Chibok gbe lọdun 2014 ati ti Dapchi lọdun 2018.

Leah Sharibu ni wọn ṣi gba pe o wa ni akata wọn.

Titi di isinyi ni ijọba Naijiria labẹ akoso aarẹ Buhari ṣi n kede pe awọn ti bori Boko Haram.

Wọn ni iwọnba perete ikọlu wọn lasan lo kan n ṣẹlẹ lasiko yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBoko Haram yóò dá Leah sílé

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí