Mohammed Yusuf: Àwọn ohùn tó yẹ kí o mọ nípa olùdásílẹ̀ Boko Haram

Mohammed Yusuf
Àkọlé àwòrán Mohammed Yusuf: Àwọn ohùn tó yẹ kí o mọ nípa olùdásílẹ̀ Boko Haram

Bi onirese ba ni oun ko fingba mọ eyi to ti fin silẹ ko ni parun laelae lọrọ Mohammed Yusuf to jẹ oludisilẹ ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram.

Ni ọdun 2002 lo da ẹgbẹ Ahlu Sunna Waljama Wal-Jihad silẹ nilu Maiduguri ti o ti n ṣe iwaasu eleyi to pada wa kale kako ni ipinlẹ naa.

Awọn to mọ Mohammed Yusuf ni o jẹ ẹni kan ti ọrọ da lẹnu rẹ ti pupọ awọn eeyan a si ma tuyaya lati gbọ waasi rẹ.

Abule Girgir ni Jakusko ni ipinlẹ Yobe ariwa ila oorun Naijiria ni wọn ti bi Yusuf lọdun 1970.

Kini wáàsí Yusuf maa n dá lé lórí:

Erongba Yusuf ni pe ki awọn eeyan maa tẹle ofin Sharia ninu igbesi aye wọn.

Gẹgẹ bi akọsilẹ, nkan ti o n fẹ ni Jihad.

Iwaasu Yusuf a maa da lori bi awọn olori yoo ti ṣe ṣe deede laarin awọn alaini ati awọn to ni lawujo.

Ọrọ rẹ ta daadaa leti awọn mẹkunnu ti a si ri ka pe awọn ọdọ to kawe miran naa to fi mọ awọn tori jajẹ lawujọ a ma tẹti gbọ waasi rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBoko Haram yóò dá Leah sílé

Ko si iye meji pe Yusuf tako ẹkọ igbalode eleyi to ni o jẹ ''haramu'' nitori pe awọn ilana rẹ ko ba ti ofin Ọlorun Sharia mu.

Nigba ti yoo fi di nnkan bi ọdun melo kan, Yusuf ti ni awọn ọmọ ẹyin pupọ ti awọn to wa ni ijọba nipinlẹ Borno si ti n kan si i lati le mu anfaani ba wọn lasiko idibo tori awọn ero to n tẹle e.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOdumakin: awọn alagbara lo wa lẹyin ijinigbe Dapchi

Iku Yusuf ati àná rẹ:

Lọdun 2009, awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram yabo ileeṣẹ ọlọpaa ni ilu Borno ti wọn si bẹrẹ si ni i ṣe ikọlu pẹlu awọn agbofinro.

Ohun ti wọn lo faa tawọn fi ṣe bẹẹ ni bi awọn agbofinro ti ṣe yinbọn pa awọn ọmọ ẹgbẹ wọn.

Nigba ti wahala naa yoo fi dẹkun, ọpọ ẹmi lo ti lọ si i ti awọn ọlọpaa si kede iku Mohammed Yusuf to wa ni ahamọ lọdọ wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌmọbinrin Dapchi: Mi o lọ sile iwe mọ

Ohun tawọn ọlọpaa sọ nipa iku Yusuf ni pe igba ti ikọlu waye ni o faragbọta.

Awọn ajafẹtọ ẹni bẹnu ẹtẹ lu iha ti awọn ọlọpaa kọ si iṣẹlẹ yii ati bi wọn ti ṣe ṣeku pa ana Mohammed Yusuf, iyẹn Baba Fugu Mohammed ni ipakupa.

Ile ẹjọ to dajọ lori iku ana Yusuf lẹyin igba naa dajọ ẹbi fawọn ọlọpaa ti awọn mọlẹbi rẹ si sọ fun BBC pe inu awọn dun si idajọ naa ati bi ile ẹjọ ti ṣe paṣẹ ki ọlọpaa san owo itanran $665,000.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionShiite: Ẹ̀mí àti ara wa kọ ohun tí ìjọba ń ṣe sìwa láti 2015

Boko Haram loni:

Lẹyin iku Yusuf, pupọ ninu awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram fọn kaakiri.

Nigba ti wọn yoo fi pada toro toro ni wọn ba de ti Abubakar Shekau si kede ara rẹ gẹgẹ bi olori ẹgbẹ naa.

Ni oorun oni to mọ, ọpọ ẹmi ati dukia lo ti ba ikọlu laarin Boko Haram ati ijọba Naijiria lọ.

Ọpọ ti di alaini ile lori ti karakata lagbegbe ibi ti Boko Haram ti n ṣoro ti dẹnukọlẹ lariwa Naijiria.

O ti pe ọdun mẹwaa bayi ti gbogbo rẹ bẹrẹ.

Ijọba lawọn ti rẹyin Boko Haram ṣugbọn bi wọn ti ṣe n da oro loore-koore ko jẹ ki ara ilu le sọ boya opin ti de ba Boko Haram.