Kemi Afolabi: Dókítà ní ìrìnàjò wákàtí mẹ́jọ láti Mecca sí Medinah ló fa ibà

Kemi Afolabi Image copyright kemiafolabiadesipe

Ara kii se okuta, igbakuugba si lo lee beere itọju lọwọ ẹni.

Bẹẹ lọrọ ri fun gbajugbaja osere tiata lobinrin, Kẹmi Afọlabi Adesipẹ, ẹni to dubulẹ aisan nilu Mecca lasiko to n kopa ninu isẹ Hajj fun tọdun yii.

Gẹgẹ bi iroyin kan latẹnu awọn eeyan to n kopa nilu Mecca ti wi, wọn ti gbe osere tiata naa lọ sile iwosan nigba ti ara rẹ ko da pe mọ lati tẹsiwaju pẹlu isẹ hajj naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIya Adura Esther Ajayi sọ àṣírí owó rẹ̀ tó fi ń ṣàánú

Iroyin ọhun salaye pe, Kẹmi lo ti n safihan pe ojojo n se ogun oun lati ilu Medinah, to si sun sinu ọkọ lasiko ti awọn olujọsin yoku lọ wo awọn ibudo manigbagbe to wa nilu Medinah.

Nigba to n salaye koko ohun to n se Kẹmi Afọlabi, dokita kan to kọwọrin pẹlu awọn arinrinajo hajj to wa latilu Eko, Abideen Aro, sọ pe awọn ami ti osere tiata naa n fihan ni iba, ori fifọ, ailee jẹun daada ati ko maa rẹ.

Dokita Aro ni, ni kete ti oun ti kofiri awọn ami aipe ara naa, ni oun ti fi to olori ikọ isegun to wa lati ipinlẹ Eko leti, tawọn si gbe lọ sile iwosan pẹlu ọkọ alaisan pajawiri, nibi ti wọn ti fidi rẹ mulẹ pe aisan iba ni Kẹmi ni, ti wọn si fun ni abẹrẹ fun ọjọ mẹta.

Image copyright kemiafolabiadesipe

"A ti sekilọ fawọn arinrinajo Hajj lati orilẹ-ede Naijiria pe ki wọn lo awọn oogun to n dena iba sugbọn o se ni laanu pe nitori ọkan rẹ to foo, Kẹmi Afọlabi ko lo oogun kankan."

Dokita naa fikun un pe, o seese ko jẹ pe irinajo tawọn eeyan to n sisẹ Hajj rin lati ilu Mecca si Medinah eyi to to wakati mẹjọ, lo fa sababi aisan osere tiata naa.