Boris Johnson: Olukemi Olufunto Badenosh di mínísítà ní London

Olukemi Olufunto Badenosh Image copyright Olukemi Olufunto Badenosh

Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Boris Johnson ti yan ọmọ Yoruba atata kan, Olukemi Olufunto Badenosh, gẹgẹ bii ọkan lara awọn minisita rẹ.

Badenosh yii lo jẹ ọmọ ẹgbẹ oselu Conservative ati ọmọ ile asofin apapọ nilẹ Gẹẹsi, eyi to n soju ẹkun idibo Saffron Walden.

Olukemi Olufunto Badenosh, tii se ẹni ọdun mọkandinlogoji ni Boris Johnson yan gẹgẹ bii minisita fun awọn ọmọde ati mọlẹbi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lara ojuse minisita tuntun yii si ni sise agbekalẹ ofin to nii se pẹlu igba ewe awọn ọmọde, abẹwo wọn ati ofin to de akoso wọn.

Nigba to n kede iyansipo tuntun naa ni oju opo Twitter rẹ, Olukemi Olufunto Badenosh @KemiBadenoch fi idunnu rẹ han si ipo nla ti Olootu ijọba Gẹẹsi yan si ọhun.

"Pẹlu iwa irẹlẹ ni mo fi gba ipo minisita kekere ti wọn yan mi si. Anfaani nla ni eyi fun mi lati sisẹ sin, ki n si mu iyatọ rere ba ọpọ isẹlẹ to n waye eyi to jẹ mi logun. Mo n fi oju sọna lati sisẹ pẹlu ikọ awọn minisita ati ẹnikọọkan to wa lẹka eto ẹkọ nilẹ Gẹẹsi."

Image copyright Olukemi Olufunto Badenosh

Ọṣu Kinni ọdun 1980 ni wọn bi Olukemi Olufunto Badenosh. Orukọ baba ati iya rẹ ni Fẹmi ati Feyi Adegoke.

Ilu Eko ati ilẹ Amẹrika lo ti lo igba ewe rẹ, ko to di pe wọn gba ilẹ Gẹẹsi lọ nigba ti Olukẹmi wa lọmọ ọdun mẹrindinlogun.