MKO Abiola: Buhari ní Abiọla kò bá dènà ìṣòro ẹ̀sìn àti ẹ̀yá ní Nàíjíríà

MKO Abiola Image copyright Getty Images

"To ba jẹ pe Abiọla wa laye ni, ọrọ aawọ ẹlẹsinjẹsin tabi ẹlẹyamẹya ko ba ti sẹlẹ lorilẹede Naijiria lasiko yii, paapa to ba jẹ pe wọn gbaa laaye lati jẹ aarẹ Naijiria ni."

Eyi ni ọrọ to ti ẹnu aarẹ orilẹede yii, Muhammadu Buhari jade lasiko to n gbalejo awọn eekan ọmọbibi ipinlẹ Ogun, to fi mọ gomina wọn, Dapọ Abiọdun ati igbakeji rẹ, Noimot Salakọ, eyi to waye nile ijọba nilu Abuja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lara awọn eekan miran lati ipinlẹ Ogun to se abẹwo si aarẹ Buhari ni arẹmọ oloogbe MKO Abiọla, Kọla Abiọla, ọmọ Abiọla obinrin, Hafzat Abiọla, gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun, Oloye Olusẹgun Ọsọba, awọn ọba alaye ati awọn eeyan jankanjankan miran.

Image copyright @MBuhari

Buhari, lasiko to n gbalejo awọn eeyan yii ni Abiọla ati igbakeji rẹ ti wọn dijọ dije, ni wọn jẹ Musulumi, bẹẹ ni aawọ ẹsin tabi ti ẹyako ba ti waye, nitori Kanuri ni ẹni to dije bii igbakeji Abiọla, ti oun naa si jẹ ilumọọka yika Naijiria.

Image copyright @MBuhari

O fikun pe Abiọla lo awọn ohun alumọsni ti ọba oke fi jinki rẹ ati gbogbo agbara to ni lati fi gba awọn ọmọ Naijiria niyanju pe ohun kan soso ti oun n fẹ ni orilẹede Naijiria ti yoo duro digbi, ko si si ohunkohun miran ti oun n wa.

Image copyright @MBuhari

Buhari salaye pe oun mọọmọ fi papa isere idaraya ilẹ wa sọri oloye MKO Abiọla ni, nitori oun nigbagbọ pe awọn ọdọ lọjọ ọla, yoo fẹ mọ idi ti wọn se fi papa isere nla naa sọri MKO Abiọla.

Nigba to n ki aarẹ, gomina ipinlẹ Ogun, Dapọ Abiọdun ni awọn eekan ọmọ bibi ipinlẹ Ogun tọ Buhari wa, lati wa dupẹ lọwọ rẹ, fun iyi ati ẹyẹ to fun Abiọla nitori ẹni ta se loore, ti ko dupẹ, bi ọlọsa ko ni lẹru lọ ni.