Seyi Makinde: Iléẹjọ́ ní àwọn alága ìbílẹ̀ kó gbọdọ̀ gbé ìgbésẹ̀ kankan títí ìdájọ́ iléẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn

Seyi Makinde Image copyright Facebook/Seyi Makinde

Ileẹjọ ti fun Gomina Ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde laṣẹ lati yan awọn alaga tuntun si awọn ijọba ibilẹ mẹtalelọgbọn to wa nipinlẹ naa.

Agbẹjọro to n ṣoju ijọba ipinlẹ Oyo lori ẹjọ ọhun, Adeniyi Farintọ to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe, agbẹjọro awọn alaga ko yọju sile ẹjọ lonii ọjọ Iṣẹgun.

O sọ pe, agbẹjọro awọn alaga ìjọba ibilẹ naa bẹbẹ pe ki adajọ sun igbẹjọ naa di oṣu kẹwaa, ṣugbọn agbẹjọro ipinlẹ Oyo tako ẹbẹ naa.

Agbẹjọro Farintọ ni agbẹjọro awọn alaga ibilẹ naa fẹ maa fi akoko ṣofo lori ẹjọ ọhun ni, ileẹjọ si gba pẹlu wọn.

Ẹwẹ, saaju ni amofin Farintọ ati ikọ rẹ ti wọn n ṣoju ipinlẹ Oyo, ti kọkọ rọ ileẹjọ lati fofin de awọn alaga naa, ki wọn ma baa le gbe igbesẹ kankan titi di igba ti ileẹjọ kotẹmilọrun yoo fi dajọ.

Ileẹjọ ṣi gba pẹlu awọn pe, awọn alaga ko le pada si ipo wọn, bẹẹ ni wọn ko le ṣe ohunkohun titi digba ti igbẹjọ yoo fi waye nibi oṣu meji si akoko yii.

Agbẹjọro Farintọ fikun ọrọ rẹ pe iru ẹjọ ti ileẹjọ kotẹmilọrun ba da lo maa sọ boya awọn alaga ti Gomina ipinlẹ ba yan lo maa ṣakoso awọn ijọba ibilẹ tabi awọn alaga to wa nibẹ tẹlẹ ki ijọba tuntun to de.