Jesus in Kenya:Ta ni ọkùnrin tí wọ́n ń pè ní ayédèrú Jesu yìí gan an?

Michael Job Image copyright Other

Ọpọ aworan ati fidio to n ṣafihan ọkunrin kan to wo aṣọ bi Jesu Kristi, ti lu oju ayelujara pa lẹnu ọjọ mẹta yii kaakiri ilẹ Afirika.

Ṣugbọn ta ni ọkunrin yii to n pe ara rẹ ni Jesu gan an, ati pe kinni o n ṣe kaakiri ilẹ adulawọ?

Ọpọ eeyan lo ti n pin aworan ati fọnran ọkunrin yii lori ayelujara, koda aṣofin kan lorilẹede South Africa, Julius Malema sọ pe, alufa ijọ kan lorilẹede ọhun gbalejo Jesu yii, lati wa ṣe iwaasu ninu ijọ rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ, awọn aworan to lu ayelujara pa ọhun wa lati ibi ayẹyẹ kan niluu Kiserian, lagbegbe Nairobi lorilẹede Kenya.

Orukọ ọkunrin eke Jesu yii ni Michael Job, o jẹ ọmọ orilẹede Amẹrika. Oniwaasu ni, bakan naa lọ jẹ oṣere tiata.

Ilu Orlando nipinlẹ Florida ni ọkunrin ọhun n gbe, nibi to ti n ṣe bii Jesu.

Image copyright Other

Isọ ti wọn ti n ta aga ijoko ati nnkan ọgbin lo wa ninu fidio to fi sita lori oju opo Facebook rẹ.

Ọpọ eeyan lori ayelujara lo ti n fi awọn aworan ọkunrin yii ṣe ẹfẹ ati bi awọn alufa ijọ kan nilẹ Afirika, ṣe maa n ṣe iṣẹ iyanu.

Ọkan lara awọn aworan yii ṣafihan bi alufa kan lorilẹede Kenyan sẹ sọ wi pe, oun ri Jesu to rin loju popo ni Kenya.

Michael Job ṣeleri wi pe, oun n ṣiṣẹ iyanu ati imularada ninu awọn fọnran iwaasu rẹ lorilẹede Kenya, bo tilẹ jẹ pe ọpọ lo koro oju si ọrọ yii.

Kii ṣe igba akọkọ ree ti Ọgbẹni Job wa si ilẹ Afirika, o ti wa si orilẹede Togo nibẹrẹ ọdun yii ṣugbọn ko wọ iru aṣọ bayii nigba naa, kootu lo wọ.