Olubadan: Ìpàdé àláàfíà wáyé láàrin Olubadan àti àwọn àgbà ìjòyè tí Ajimobi sọ di ọba.

Olubadan ati awọn ijoye rẹ Image copyright Twitter/Local blog

Lẹyin oṣu mẹrindinlọgbọn ti ede aiyede ti waye laarin Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Saliu Akanmu Adetunji, Aje Ogungunnisọ Kinni, ati awọn ijoye rẹ ti gomina tẹlẹ nipinlẹ Oyo, Abiọla Ajimọbi gbe ade le lori, ija ti pari.

Eyi jẹyọ lasiko ti awọn ijoye naa wa si aafin Olubadan to wa ni adugbo Popoyemọja nilu Ibadan, ti ọkọọkan wọn ko si de ade.

A gbọ pe tilu-tifọn ni Olubadan fi ki awọn ijoye rẹ ọhun kaabọ pada s'aafin, ti Olubadan si sọ fun awọn ijoye naa pe, oun fi aaye gba ipade ipẹtu saawọ ọhun nitori alaafia, iṣọkan ati ilọsiwaju ilu Ibadan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣaaju asiko yii ni Olubadan ti paṣẹ pe, eyikeyi awọn ijoye naa ko gbọdọ wa si aafin oun fun ipade pẹlu ade ọba lori.

Ede aiyede naa bẹrẹ lasiko ti Gomina Abiọla Ajimọbi mu ayipada ba ilana jijẹ oye Olubadan lọdun 2017, to si sọ awọn ijoye mọkanlelogun di ọba alade.

Ọdun 1957 ni ofin oye jijẹ nilu Ibadan ti wa fun lilo.

Ọrọ naa mu ki ọpọlọpọ awuyewuye waye laarin awọn ọmọ bibi ilẹ Ibadan nile ati lẹyin odi. Ọpọ lo koro oju si igbesẹ ti Gomina Ajimọbi gbe, pe o fẹ ẹ pa ilana ti awọn baba nla ilẹ Ibadan da silẹ da.

Bo tilẹ jẹ pe ijọba Ajimọbi ni oun ti ṣe ipade ati ijiroro pẹlu igbimọ lọbalọba ki oun to gbe igbesẹ naa, amọ Olubadan ati Osi Olubadan, Oloye Rashidi Ladoja tako igbesẹ naa, ti ọrọ si di ti ile ẹjọ, laarin aafin Olubadan ati ijọba ipinlẹ Oyo.

Nibayii, ọjọ kọkandinlogun oṣu Kẹjọ,ọdun 2019 ni ipade miran yoo tun waye ni aafin laarin Olubadan ati awọn ijoye rẹ.

Related Topics