Community Policing: ìjọba ìbílẹ kọọkan yóò gbà ààdọta òsìsẹ

asia olopaa Image copyright Policeng
Àkọlé àwòrán Community Policing: ìjọba ìbílẹ kọọkan yóò gbà ààdọta òsìsẹ

Gbogbo ijoba ibile merinleniaadorino le ni eedegbeje ni eto naa yoo ti waye.

Ìlé iṣẹ ti kẹde láti gba àwọn òṣiṣẹ ẹgbẹrún lónà ogójì tí yóò maa ṣe ọlọpàá àdúgbò tí àwọn ọmọ Nàìjíríà tí ń pè fún kí ọrọ ètò ààbò òrílẹ-èdè yìí tó dé ibi ti ó de dúró yìí.

Ìlé iṣẹ ọlọpàá ní àwọn yóò gba òsìṣẹ kọọkan láti àgbègbè tí wọn bá n gbé, ó kéré tán ẹnìyàn ààdọtá láti ìjọba ìbìlẹ kọọkàn jákejádò orílẹ-èdè Nàìjíríà

Bákan náà ni wọn fí kún un pé ènìyàn ọọdúnrún lé ni ẹgbẹrún ní àwọn ní yóò gbà sísẹ nínu àwọn akọṣẹmọṣẹ àti àwọn ẹgbẹ ọdọ ní Nàìjíríà.

Lórí òpò twitter ilé iṣẹ olopaa ní ìròyín náà ti jáde.

Bakan náà ni ọgá àgbà ọlọpàá Muhammed Adamu kédé rẹ nínú ìpàdé kan to pé fún àwọn ọgá ọlọpàá nílu Abuja níbi tó ti sàlàyé kíkún lóri fífòfin dé àwọn ọmọ egbẹ Shi'ite tó ń tèlé El-ZakyZakky, olori Islamic Movement in Nigeria (IMN).

O menuba igbese ijoba ti yoo jade laipe.

Iléẹjọ́ fún Seyi Makinde láṣẹ láti yan adelé alága ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Oyo

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJoke Silva: Olu, ó tó gẹ́ pẹ̀lú obìnrin yìí níkan tó ń ba ẹ ṣeré ìfẹ́ nínú sinimá