Tanker Accident: Ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń lọ sẹ́nu iṣẹ́ àti okoòwò ló tàn sílẹ̀

Opopona marosẹ Ibadan si Eko di pa Image copyright @Gidi_Traffic

Se ni ohun gbogbo lọju pọ ni opopona Eko si Ibadan lọjọru, ti awọn ero si duro gogogo soju popo lai ri ọkọ wọ lasiko ti ọkọ epo kan to ko epo disu danu soju popo.

Ori afara gbọọrọ ti wọn n pe ni Long Bridge, nibudokọ Barewa lopopona Ibadan silu Eko ni isẹlẹ naa ti waye eyi to mu ko nira fun awọn ọlọkọ to n bọ lati oju ọna marosẹ Eko si Ibadan lati kọja.

Koda, ọrọ yii kanlẹ, o tun kan baale nitori awọn olugbe adugbo Mowe, Ibafo, Asese, magboro ati Arepo, to yẹ ko lọ wọ isẹ ni aarọ yii ni sunkẹrẹ fakẹrẹ ọks mu mọlẹ, ti wọn ko si lee lọ sẹnu isẹ ati okoowo wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ sa, awọn osisẹ ajọ ẹṣọ oju popo, awọn ọlọpa atawọn ẹsọ to n ri si igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Eko ni wọn duro si adugbo naa lati ri daju pe ijamba ko waye.

A tun gbọ pe awọn osisẹ ileesẹ Julius Berger to n tun oju sna se lo wa nibẹ lati ko awọn epo to danu ọhun, ti ọrọ yii ko si yọ awọn osisẹ panapana silẹ pẹlu aibaamọ ijamba ina lee fẹ waye.