Ooni: Ọọni àti Buhari tún ṣèpàdé fún ìgbà kejì láàrin ọ̀sẹ̀ kan

aworan Ooni Image copyright @Bashir Ahmad

Ọọni ile ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi ti sọ pe ijọba Naijiria ti n ṣe eto, lati ṣe amulo ẹrọ dironu ati CCTV gẹgẹ bi ohun elo lati daabo dukia ati ẹmi awọn eeyan ilẹ kaarọ ojiire.

Ọọni fi ọrọ yii lede lẹyin ipade ti oun ati awọn ọba alade lati agbegbe naa se pẹlu aarẹ Buhari nile ijọba.

Gẹgẹ bi ohun ta gbọ, aarẹ Buhari ti tẹwọgba aba lati ma sọ awọn igbo kijikiji to wa nilẹ Yoruba pẹlu awọn irinṣẹ aabo igbalode.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIya Adura Esther Ajayi sọ àṣírí owó rẹ̀ tó fi ń ṣàánú

Ọba alade naa sọ pe, wọn yoo ṣe agbekalẹ ẹrọ ayaworan CCTV kaakiri opopona marosẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ipade yii to waye lọjọru ni ẹlẹkeji iru rẹ ti yoo waye laarin ọsẹ kan, ti wọn lero pe yoo wa ojutu si ipenija aabo to ba awọn ipinlẹ guusu iwọ oorun.