Iya Adura Esther Ajayi sọ àṣírí owó rẹ̀ tó fi ń ṣàánú fún BBC
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Esther Ajayi: Èmi náà ti borí ìṣòro rí ló ń mu mi ṣojú àánú

"Ọlọ́run ló fún èmi ní oreọ̀fẹ́ àti máa f'owó ṣàánú".

Ko tii to ọpọlọpọ ọdun rara ti okiki Esther Ajayi ẹni ti gbogbo eniyan mọ si Iya Adura bẹrẹ si nii tan kaakiri agbaye gẹgẹ bi olowo to n ṣ'aanu t'ẹru t'ọmọ.

N30,000 ni mo gbà fún orí, ọwọ́ àti ẹran ara wòlíì Bosede - Kayeefi

Boko Haram àti àwọn Fulani daran daran jẹ́ ọgbọ́n áti sọ Nàíjíríà di ìlú mùsùlùmí - Wale Oke

O ni ọrọ iṣoro ti Ọlọ̀run jẹ ki emi naa bori lo jẹ kaa bẹrẹ Esther Ajayi Foundation.

O ṣalaye pe niwọn igba ti iwadii awọn ba ti jẹ ootọ pe eeyan kan nilo iranwọ, awọn maa n tete ṣe e fun wọn.

"Awọn eeyan maa n san idamẹwaa to wuwo gan fun mi, iyẹn lemi naa ṣe n ribi ṣ'oore".

Iya Esther ni ẹni ti o ba n gba idamẹwaa ti ko ṣe ore tabi, ṣaanu, ki a fi silẹ sọwọ Ọlọrun. O ni "ṣugbọn bibeli sọ pe ka mu idamẹwaa wa, emi naa si n san temi".

Awọn Iroyin mii ti ẹ le nifẹ si