Shiite: Suhaila El-Zakzaky ní ẹgbẹ́ àwọn kọ́ ló kéde àti dáwọ́ ìwọ́de dúró

Aworan ọmọ ẹgbẹ́ Shiite ti'n fẹ̀hónú han. Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn ọmọ ẹgbẹ́ Shiite n fẹ̀hónú hàn fún ìtúsílẹ̀ olori wọn Sheikh Ibrahim Zakzaky.

Ọrọ gba ọna mi yọ nigba ti ọmọbinrin olori ẹgbẹ Shiite, Ibrahim El-Zakzaky to wa ni ahamọ sọ pe, ẹgbẹ awọn ko kede lati dawọ duro lori iwọde ti ẹgbẹ́ shiite n se.

Suhaila Ibrahim El-Zakzaky, ninu fidio to fi sita loju opo Twitter rẹ salaye pe, iwọde ẹgbẹ naa to da lori pe ki wọn tu El-Zakzaky silẹ, ṣi n tẹ siwaju

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lọjọru ni iroyin gbode pe, aarẹ igbimọ to wa feto iroyin fẹgbẹ Shiite, Ibrahim Musa fi atẹjade ṣọwọ pe awọn so iwọde naa rọ, ti awọn si ṣetan lati gbe ijọba Naijiria lọ si ile ẹjọ lori bo ti ṣe pe wọn ni agbesunmọmi.

Suhaila ninu fidio naa ni, Musa ko le gbẹnu awọn sọrọ ati pe iwọde yoo ṣi tẹsiwaju.

O ti to ọdun marun un bayi ti aawọ ti n waye laarin ẹgbẹ Shiite ati ijọba Naijiria lori idande olori wọn, Ibrahim El Zakzaky.

Image copyright @SZakzakyOffice/Twitter

Awọn ọmọ ẹgbẹ naa si ti n ja fun itusilẹ olori wọn to ti wa ni atimọle lati ọdun 2015 toun ti pe ile ẹjọ giga mi Abuja paṣẹ ki wọn tu silẹ.

Lẹnu lọlọ yii, iwọde ẹgbẹ naa ti n lagbara ti awọn eeyan kan si ti padanu ẹmi wọn nitori rẹ.

Suhaila kasẹ ọrọ rẹ ninu fidio naa pe, ''ẹni to fi atẹjade sita pe awọn wọgile iwọde ko ni nnkankan ṣe pẹlu awọn to n ṣagbatẹru iwọde to n lọ lọwọ ni Abuja, ti iwọde naa ko si ni dopin ayafi ti wọn ba tu olori awọn silẹ''

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionShiite: Ẹ̀mí àti ara wa kọ ohun tí ìjọba ń ṣe sìwa láti 2015