Timothy Omotosho: Ó pàdánù ìwé ìgbélú ní South Africa t'orí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀

Timothy Omotosho Image copyright Soweta/getty images

Ẹjọ kotẹmilọrun ti ọmọ orilẹede Naijiria kan, to jẹ oniwaasu ori amohunmaworan ni South Africa, pe tako idajọ to sọ pe o ti padanu iwe igbelu rẹ ti foriṣanpọn.

Ojisẹ Ọlọrun naa lo n n jẹjọ ẹsun ifipabanilopọ ati ṣiṣe fayawọ ọmọniyan nile ẹjọ kan ni Port Elizabeth lọwọ.

Timothy Omotosho, to jẹ oludasilẹ ijọ Jesus Dominion International church l'orilẹede South Africa, ni wọn sọ fun l'Ọjọbọ pe, gbigbe rẹ ni orilẹede naa ti tako ofin bayii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Asiko ti igbẹjọ n lọ lati gba oniduro rẹ lori ẹsun ti wọn fi kan an ninu oṣu Kẹrin, ọdun 2017, ni ileeṣẹ ijọba to n mojuto ọrọ mọlẹbi ti kọkọ sọ fun pe, o ti padanu ẹtọ to ni lati maa gbe ni South Africa.

Idi si ree ti Ọmọtọsọ fi pe ẹjọ kotẹmilọrun lati tako aṣẹ naa.

Bo tilẹ jẹ wi pe ipa ti eyi yoo ni lori Omotosho ko ti i fi bẹẹ fi oju han, igbẹjọ rẹ yoo tun pada bẹrẹ lọjọ Iṣẹgun lẹyin ti igbẹjọ akọkọ dojubolẹ.

Eyi ri bẹẹ nitori bi adajọ to n gbọ ẹsun naa yọ ọwọ kuro ninu ẹjọ ọhun nitori o da bi ẹni pe o ṣeeṣe ko ṣe ègbè.

Ọmọ ijọ rẹ kan, Cheryl Zondi, to ti pe ẹni ọdun mejilelogun bayii lo fi ẹsun kan an l'ọdun 2018 pe o fi ipa ba oun ni ibalopọ lati igba ti oun ti pe ọmọ ọdun mẹrinla.

Image copyright Soweta/getty

Omotosho si sọ nigba naa pe, oun ko jẹbi ẹsun naa.

Lọjọ ti igbẹjọ kọkọ waye, wọn ṣe afihan rẹ lori amohunmaworan, eyi ti ko waye ri ni orilẹede South Africa.

Bakan naa ni ọpọlọpọ eniyan yabo ile ijọsin rẹ lasiko naa, ti wọn ko si jẹ ki wọn raaye ṣe isin.

Iwe iroyin ori ayelujara kan, NCA sọ ni Ọjọru pe agbẹjọro rẹ ti kọkọ sọ pe diẹ lara awọn ẹsun ti wọn fi kan Omotosho ko lagbara to nkan ti onibaara oun yoo wi awijare le lori, ṣugbọn adajọ to gbọ ẹjọ naa fagile ẹbẹ rẹ.

Bakan naa ni akọroyin kan ni South Africa fi fidio kan, to ṣafihan awọn alatilẹyin pasitọ naa nibi ti wọn pejọ si niwaju ile ẹjọ ni Port Elizabeth.