Lamellar Ichtyosis: Kóòmù ni wọ́n fi ń họra fún Amida nítorí bí àwọ̀ rẹ̀ ṣe rí

Lamellar Ichtyosis: Kóòmù ni wọ́n fi ń họra fún Amida nítorí bí àwọ̀ rẹ̀ ṣe rí

Arun ti ko gboogun, ki Eledua ma fi kan wa.

Bẹẹ lo jọ pe ọrọ ọmọdebinrin kan ti BBC ṣe alabapade ti ṣe ri nitori arun to mu ki awọ rẹ maa ṣi bi ti ẹja.

Arabinrin Latifat Sulaiman ni Eledua fi ọmọ yi kẹ ṣugbọn lati igba to ti ni oyun rẹ sinu ni o ti n mọ inira.

''Niṣe ni inu mi maa n gbona nigba ti mo loyun Hameeda. Nigba ti wọn yoo yọ ọ jade naa bi igba pe o jade lati inu omi gbona ni''

Awọn onimọ iṣegun Dokita Ayesha Akinkuugbe pe orukọ aarun to n mu ki awọ Hameeda maa ṣi bi ti ẹja yi ni Lamellar Ichtyosis.

Oniṣegun itọju awọ ara yi tẹsiwaju pe o ṣọwọn ki eeyan to ri iru rẹ ko mu eeyan.

Koko kan pataki ti wọn sọ fun BBC ni pe ko ni oogun ti wọn le fi wo o itori pe ko le lọ lara ẹni to ba mu.

Idẹyẹsi ati itabuku jẹ nkan ti arabinrin Latifat Sulaiman n koju nitori ipenija to de ba ọmọ rẹ yii.

O ṣalaye pe ko le lọ si ileewe mọ nitori awọn akẹgbẹ rẹ maa n fi ṣe yẹyẹ lọpọ igba ni.

''Iṣẹ ransọransọ ni mo n ṣe ṣugbọn nitori Hameeda pupọ awọn alabara mi ni ko wa si ṣọọbu mi mọ''

Lọwọlọwọ inu inira ni Hameeda wa nitori awọ rẹ a maa yun ti o si ni lati maa fi koomu họ ara.

Yatọ si eleyi, o tun n ko ipenija oju ati ẹsẹ rẹ ti wọn ko duro deede.