Revolution protest: Àjọ DSS ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi gbé Sowore

Aworan Sowore Image copyright omoyele

Ajọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ DSS ti fidi rẹ mulẹ pe lootọ, oun l'oun mu oludije fun ipo aarẹ tẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu African Action Congress, Omoyele Sowore si ahamọ.

Ọgbẹni Sowore, to jẹ oludasilẹ ileeṣẹ iroyin Sahara Reporters, jẹ ọkan lara awọn to ṣe agbatẹru iwọde kan ti ẹgbẹ Global Coalition for Security and Democracy in Nigeria, fẹ ẹ ṣe ni ọjọ Aje, ọjọ karun un oṣu Kẹjọ ọdun 2019 ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe "ete iditẹ gba ijọba ni iwọde naa."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Agbẹnusọ fun ajọ DSS, Peter Afunaya sọ fun BBC pe, awọn lọ ọ gbe oludasilẹ iwọde naa, ti wọn pe 'Revolution Now' ni owurọ ajọ Abamẹta to kọja, nitori pe oun n pe fun iditẹ gba ijọba.

Ṣaaju ọjọ naa ni ikọ Coalition for Revolution ti Sowore da silẹ, ke si awọn ọmọ Naijiria kaakiri orilẹede yii lati jade si igboro, ki wọn si beere fun opin si aisi aabo ni Naijiria.

Image copyright @YeleSowore

Ẹgbẹ naa tun n beere fun ẹkọ ọfẹẹ, ati eto ilera fun gbogbo eniyan, ati eto ọrọ aje to dara.

Amọ ajọ DSS ko sọ boya wọn yoo mu ẹnikẹni to ba yọju fun iwọde naa l'ọjọ Aje.

Awọn ileeṣẹ iroyin kan sọ pe, agbẹnusọ ajọ DSS, Afunaya sọ pe awọn gbe igbesẹ naa ni ibamu pẹlu ojuṣe wọn l'abẹ ofin.