Snake Market: Àwọn òńtàjà ní àwọn ń sin ejò fún títà ni, wọn kìí ko nínú igbó

Snake Market: Àwọn òńtàjà ní àwọn ń sin ejò fún títà ni, wọn kìí ko nínú igbó

Ọpọ eeyan lo maa n sa fun ejo, ti wọ̀n kii si jẹ rara.

Amọ eyi ko ri bẹẹ ni ọja Agbalata nilu Badagry nitori ẹran ejo ni ojulowo ọja ti wọn n ta nibẹ.

Awọn iyalọja to ba BBC Yoruba sọrọ salaye pe, lati awọn ilu nlanla nilẹ Yoruba ni wọn ti n wa ra ẹran ejo lọdọ awọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wọn ni awọn kii ko ejo ti awọn n ta ninu igbo, awọn maa n sin ejo fun tita ni.

Bakan naa ni wọn salaye oniruuru anfaani ti ejo ati awọn ẹya ara rẹ n se fun ilera ọmọniyan.

Ẹ ba wa kalọ lati mọ ọpọ anfaani ti ejo ni fun eeyan tẹẹ ba jẹ ẹ, ninu fidio yii.