Shiite: Ojú Zakzaky kan ti fọ́, májèlé sì wà nínú ara rẹ̀, ìyàwó rẹ̀ kò sì le è rìn mọ́

Awọn ọmọ ẹgbẹ Shiite to n sewọde Image copyright @Shuleman El-zakzaky

Awọn ọmọ ẹgbẹ Shiitee sọ pe idajọ ileẹjọ giga ipinlẹ Kaduna lọjọ Aje jẹ idajọ ododo to lodi si iwa ika ati iwa tani yoo mu mi.

Ileẹjọ fun Ibrahim El-Zakzaky ati iyawo rẹ ni beeli lati lọ tọju ara wọn lorilẹede India, bo tilẹ jẹ pe ileẹjọ naa paṣẹ pe kawọn to n ṣeto igbẹjọ tẹ wọn lọ.

Alaga igbimọ awọn ọmọ ẹgbẹ Shiite ti wọn ti n ṣewọde, eyi ti wọn fi n sọ fun ijọba lati fun olori wọn ati iyawọ rẹ lominira, Abdurrahman Abububakar Yola ni, ẹgbẹ Shiite nigbagbọ ninu titẹle ofin ati lilepa alaafia lati yanju aawọ lai lo ipa bo tilẹ jẹ pe ijọba mọọmọ bi awọn ninu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹ o ranti pe El-Zakzaky ati iyawo rẹ beere fun beeli nitori wọn ṣaisan latimọle ti wọn wa nitori ijiya tawọn ologun fi jẹ awọn mejeeji.

Ẹgbẹ Shiite tun sọ ninu atẹjade ti wọn fi sita pe, bi wọn ti fi El-Zakzaky ati iyawo rẹ mọle nile iṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lodi si ẹtọ ọmọniyan.

Wọn tun fẹsun kan ile iṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ pe wọn fun un awọn mejeeji ni mọjele jẹ latimọle, ti oju olori awọn kan si ti fọ nigba ti iyawo rẹ ko lee da rin funra rẹ mọ lai lo kẹkẹ ti wọn fi n tii kiri.

Image copyright Getty Images

Ẹgbẹ naa ni gbogbo ijiya yii latimọle ti jẹ ki El-Zakzaky ati iyawo rẹ ni aarun rọpa-rọsẹ lọpọ igba, eyi si n jẹ ki ẹru maa bawọn pe aarun yii tun le pada ṣe wọn.

Wọn ni oju El-Zakzaky kan fọ nitori ijiya tawọn ologunh fi jẹẹ, ati pe ekeji naa tun le fọ ti ko ba ri itọju gidi lasiko.

Ìtàn ìkọlù ẹgbẹ́ Shiite ní Nàìjíríà àti àwọn ìfarahàn adarí wọn, Ibraheem Zakzaky níle ẹjọ́.
 • 1980s
  Ibraheem Zakzaky ló dá ẹgbẹ́ ẹlẹ́sìn Islamic Movement in Nigeria (IMN) sílẹ̀.
 • July 25, 2014
  Ìròyìn sọ pé ọmọlẹhin El-Zakzaky márùndínlógójì ni àwọn ológun yìnbọn pa lásìkò ìwọde kan ní ìlú Zaria, Kaduna. Ọmọ rẹ̀ ọkùnrin mẹ́ta wà lára àwọn tí wọ́n pa.
 • December 12, 2014
  Ọgọọrọ àwọn ọmọ ẹgbẹ IMN dí ọ̀nà mọ́ ọ̀gá àgbà àwọn ológun, Ọ̀gágun Tukur Buratai ní òpópónà Kaduna ní Zaria. Àwọn ológun fi ẹ̀sùn kan ẹgbẹ́ pro-Iranian pé wan ń gbìyànjú láti pa Ọ̀gágun Tukur Buratai èyí tí wọ́n ní irọ́ ni.
 • December 12 - 13, 2014
  Ẹ̀sùn kàn pé ilé iṣẹ́ ológun Nàìjíríà pa ǹkan bíi ọ̀ọ́dúnrún ẹlẹ́sìn Shia wọ́n sì bo òkú wọn mọ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n ilé iṣẹ́ ológun ní kò rí bẹ́ẹ̀.
 • December 14, 2014
  Àwọn ológun mú El-Zakzaky àti ìyàwó rẹ̀, Zeenat sí àtìmọ́lé ọlọ́pàá ìpínlẹ̀.
 • November 14, 2016
  Wọ́n pa ọmọ ẹgbẹ́ Shiite mẹ́jọ̀ àti ọlọ́pàá kan ní ìwọ̀de ẹ̀sìn kan ní Kano. Àwọn ọlọ́pàá dí ìwọ̀de Shia lọ́wọ́ lójúnà wọn lọ sí Zaria fún ìsìn mímọ́ ọlọ́dọọdún. Ìgbìmọ̀ tó ga jù lọ tó ń gbọ́ ẹjọ́ ẹ̀sìn Islam lórílẹ̀èdè Nàìjíríà (NSCIA) ṣèbẹ̀wò sí adárí IMN, Ibraheem Zakzaky látìmọ́lé ní Abuja.
 • December 2, 2016
  Ile ẹjọ giga julọ ni Naijiria paṣẹ ki wọn tu adari ẹgbẹ naa silẹ latimọle ipinlẹ fun awọn ọlọ́pàá laarin wakati marundinlaadọta.
 • January 20, 2017
  Pẹlu bi ijọba ṣe kọ lati tẹle aṣẹ náà, ile ẹjọ giga sọ pe Ọga agba Ọlọ́paa, Ibrahim Idris, Adajọ agba Naijiria tẹlẹ ri, Abubakar Malami ati adari agba ajọ DSS, Lawal Daura ni yoo jẹbi ẹsun yii ti wọn yoo si fi ẹwọn gbara bi wọ ba tẹsiwaju lati maa kọ si ile ẹjọ lẹnu ọjọ keji oṣu kejila ọdun 2016.
 • January 7, 2018
  Akẹkọ meji ku lọwọ awọn oṣiṣẹ́ alaabo lasiko iwọde ni Kaduna, Ila Oorun ariwa Naijiria. Pẹlu bi ile jọ giga ṣe dajọ, Zakzaky di ẹni ti wọn o ri mu liriṣiriṣi ọna. Ijoba ni awọn ko laṣ lati tu Zakzaky silẹ pe iwaju ile ẹjọ ipinlẹ Kaduna ni ọrọ rẹ wa. Fun idi eyi, awọn ọmọlẹhin rẹ, IMN ni ko si iru idiwọ tabi ohun ti yoo na awọn, wọn yoo tẹsiwaju pẹlu iwọde titi wọn yoo fi tu u silẹ.
 • January 13, 2018
 • April 16, 2018
  Ìkọlù wáyé láàrín àwọn ọlọ́pàá àti àwọn ọmọ lẹyìn El-Zakzaky ti a mọ̀ sí IMN láti pè fún ìtúsílẹ̀ ọ̀gá wọ́n ní Unity Fountain Abuja, ẹni kan kú tí ọ̀pọ́ sì fara pa.
 • April 23, 2018
  Ọ́lọ́pàá nílùú Abuja tún kọlu àwọn IMN lásìkò ìwóde ti awon ajọ ajà fẹ́tọ́ ọmọ ènìyàn si sọ pé ènìyàn márundínlọ́gọ́fà ní wọn mú sí àgọ́ wọ́n
 • May 15, 2018
  El-Zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ Zeenat ní wọ́n kó wá si ìwájú ilé ẹjọ́ gíga ni ìlú Kaduna níwájú adájọ Gideon Kurada, lóri ẹ̀sù ìpànìyàn, ìpéjọpọ̀ ti kò bá òfin mu, dída omi àláfíà ìlú rú, láàrin ẹ̀sún míràn. Ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna ló gbée lọ si ilé ẹjọ́
 • July 11, 2018
  Ilé ẹjọ́ sún ìgbẹ́ja náà sí ọjọ́ kejì oṣù kẹjọ́, ọdún 2018
 • August 2, 2018
  Ilé ẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ ìtúsilẹ̀ El-Zakzaky sí ọjọ́ kẹrin, osù kẹ́wàá, ọdun 2018
 • October 4, 2018
  Ilé ẹjọ tún sún ìgbẹ́jọ ìtúsílẹ̀ rẹ̀ sí ọjọ́ kẹ́tadínlógun ọdún 2018
 • October 27, 2018
  Àwọn ọmọ ẹ̀yin El-Zakzaky, dí ojú pópó ní agbègbè afárá Zuba, Abuja. Wọ́n kojú pẹ̀lú àwọn ọmọ oogun ti wọ́n n gbé ǹkan ìjà lọ, èyí sì ló sokùnfà pípa àwọn ọmọ Shi'ite mẹ́ta.
 • October 29, 2018
  Àwọn olùfẹ̀hónú hàn tún pada fìjà pẹ́ẹ́ta pẹ̀lú àwọn ọmọ ológun àti ọlọpàá. Nígbà tí àwọn ọmọ ogun kéde pé ènìyàn mẹ́ta nínú ọmọ Shí'ite tún kú, sùgbọ́n àwọn ọmọ Shi'ite sọ pé ó lé ni èèyan ààdọtá tí àwọn ọmọ ogun pa.
 • October 30, 2018
  Irínwó àwọ́n ọmọ òògun IMN ní wọ́n tì mọ́le fún dídamú àláfíà àrá ìlú ní ìlú Abuja. Àwọn elétò ààbò fẹ́sùn kan àwọn Shia tí wọ́n gba ìgbòrò kan fún ọjọ mẹ́ta ni ìlú Abuja pé wọ́n gbe ado olro àtí àwọn ǹkan ìjà olóró míràn. Àwọ́n ọmọ ogun faramọ pé ènìyàn mẹ́ta kú, sùgọ́n àwọn IMN sọ pé ọ̀pọ̀ ènìyaǹ ní wọ́n pa
 • November 17, 2018
  Ilé ẹjọ kọ ipẹ̀jọ́ náà láti dá a sílẹ̀ àti pé kò sí ẹ̀rí àr'\idájú pé wọ́n ń ṣe àìsàn gẹ́gẹ́ bi àyẹ̀wò tí àwọ akọṣẹ́ mọ́ṣẹ́ onísègùn òyìnbó ṣe, láti gbe ìpèjọ́ wọ́n lẹ́sẹ̀.
 • December 7
  Ogúnlọ́gọ̀ àwọn olùfẹ́honúhan, gba gbogbo ìlú Abuja tí wọ́n ń pè fún ìtúsílẹ̀ olórí wọ́n
 • January 22, 2019
  Adájọ́ Gideon Kurada, pàsẹ́ fún El-Zakzaky àti ìyáwó rẹ̀ Zeenat, kí wọ́n wà nínú àtìmọ́lé àwọ́n ọtẹ̀lẹ̀múyẹ́
 • June 29, 2019
  Adájọ Kurada sún ìgbẹ́jọ síwájú láìsí gbèdéke nítori ó nílo lati jòkó fún ìgbìmọ tó ń gbọ́ ẹ́jọ tó súyọ lẹ̀yìn ìdíbo ààrẹ ní Yobe
 • July 9, 2019
  Ọlọ́pàá àti Shi'ite tún kọlu ara wọ́n níwájú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Abuja. Ilé iṣẹ̀ ọlọpàá sọ pé wọ́n yín àwọn òṣìṣẹ́ àwọn mẹ́jì níbọn lẹ́sẹ̀ tí àwọn mẹ́fà sì farapa nígbà tí àwọn Shia lá ponpo àti òkúta mọ́ wọ́n. Nígbà ti IMN sọ pé Abdullahi Muhammad Musa, sọ fún ilé ìròyìn Reuters pé àwọn ọlọpàá síná bolẹ̀ ti wọ́n sì pa ènìyàn méji láàrin àwọ́n afẹhonu han lágbà ti wọ́n ń fẹ wọ ilé ìgbìmọ aṣojúsofin ní ìrọ̀wọ́rọsẹ̀.
 • July 10, 2019
  Àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ asofin ké pe ìjọba Nàìjíríà láti fi El-Zakzaky silẹ̀ ní ìbámu pẹ́lu ìdájọ ti ilé ẹjọ dá
 • July 18, 2019
  Adájọ D.H Khobo tó paada wá gbẹ́jọ náà sún ìgbẹ́jọ náà síwájú dí ọjọ́kọkàndílọ́gbọ̀n 2019. Ó ní ''ó ṣe pàtàkì kí ẹ mọ́ pé kò sí ẹjọ́ El-Zakzaky lọ́wa ìjọba apapọ̀ mọ́ sùgbọ́n ọwa ìjọba ìbílẹ̀'' ìjẹ́jọ tó ba tí niṣe pẹ̀lú ìpànìyàn, ìjọba kìí gba oníduro, èyí ló sokùnfa ti El-Zakzaky àti ìyàwó rẹ́ ṣe n gbà ààyẹ nítori ìlera wọ́n
 • July 22, 2019
  Igbákejì Kọmisọna ọlọpàá,Umar Umar, òṣìṣẹ́ Channels, Precious Owolabi, àti àwọn ọmọ IMN tí wọ́n pa lásìkò ìwóde tí o pada yìí sí wàhálà
 • July 29, 2019
  Adájọ Darius Khobo ti ilé ẹjọ́ gíga ti Kaduna tún sún ìgbẹ́jọ sí ọjọ́ ọsùn kẹ́jọ ọdún 2019, ti El-Zakzaky àti ìyàwó rẹ̀,wọ́n si tọrọ́ ààyè láti lọ fún ìwòsàn ní orílẹ̀-èdè India. Olórí ẹ̀sìn náà kò yọjú sí ilé ẹjọ
 • July 31, 2019
  Àwwọn IMN so àdàgbá ìwóde wọn rọ̀ láti wọ́ ojútu míràn sí ẹ̀dùn ọkan wọ́n àti láti gbé ìjọba àpapọ lọ sí ilé ẹjọ́ fún pípè wọ́n ni ẹgbẹ́ agbésùmọmí.
 • August 5, 2019
  Ní bayìí ilé ẹjọ ìpínlẹ̀ Kaduna ti dá El- Zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ lóri ọ̀rọ̀ ìlera
 • August 12, 2019
  Sheikh Ibrahim El-zakzaky de si Abuja lati Kaduna ṣaaju irinajo rẹ si Inidia fun itọju. Wọn kuro ni papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe , Abuja lọ si India fun itọju ara , pẹlu awọn ọtẹlẹmuyẹ ati ẹbi rẹ diẹ.
 • August 13, 2019
  Sheikh Zakzaky de Delhi, orilẹede India fun itọju ara, Awọn oṣiṣẹ eto ilera si gbee wọ ileewosan lori aga alaaarẹ
 • August 14, 2019
  Ninu ohun kan to fi ranṣẹ to si tan ka, El-Zakzaky fẹdun sọ pe ipo ti ile iwosan orilẹede India naa wa buru ju ti ibi ti oun wa ni Naijiria lọ. Ijọba orilẹede Naijiria fẹsun kan olori ijọ IMN naa pe o ni erongba ọtọ si ilana ti wọn la silẹ fun irinajo fun itọju rẹ.
 • August 15, 2019
  Suhaila Zakzak, ọmọ El- Zakzaky ṣàlàyé fún BBC pé àwọn àyèwò ara tí Zakzaki ṣe ni Medanta Hospital fihàn pé májèlé ọta ìbọn tí àwọn ológun yìn lùú ní ọdún 2015 ń dàá láàmú.
 • August 15, 2019
  Ibrahim El-Zakzaky yóò padà sí orílẹ̀èdè Nàíjíríà láti orílẹ̀èdè India níbi tí ó ti lọ ṣàyẹ̀wò ara láì gba ìtọ́jú
 • August 16, 2019
  El-Zakzaky de Naijiria
Awọn to ṣe àkójọ yìí, Azeezat Olaoluwa, Princess Abumere, Olawale Malomo
Awọn to ya aworan yii: Getty Images.

Ẹgbẹ Shiite tun sọ pe ninu irora ti ko ṣe fẹnu sọ ni iyawo El-Zakzaky wa nitori ọta ibọn tawọn ologun yin mọ si mwa lara rẹ.

Wọn ni nitori ailera awọn mejeeji ni wọn ko fi le lọ si ileẹjọ fun igbẹjọ lati gba beeli fun wọn lẹẹmeji ọtọtọ bayii.

Ẹgbẹ Shiite tun sọ siwaju si ninu atẹjade ti wọn fi sita pe awọn ile iwosan ni Naijiria ko le ṣetọju El-Zakzaky ati iyawo rẹ ninu oniruuru aarun lo ṣe wọn latimọle ti wa lati ọjọ yii.

Image copyright Getty Images

Wọn ni afaimọ kọwọ maa bọ sori ti ileẹjọ ko ba fun wọn ni beeli lọjọ Aje.

Ẹgbẹ Shiite ni ijọba Naijiria ko bọwọ fun ofin orilẹede naa, eleyi to mu ijọba ma tẹle aṣẹ ileẹjọ wi pe ki wọn fun El-Zakzaky ati iyawo lominira.

Wọn lo atẹjade naa lati ki awọn ajafẹtọ ọmọmiyan, awọn akọroyin, ati gbogbo eeyan to gbaruku ti ẹgbẹ Shiite nigba ti wọn n ṣe iwọde lati beere idajọ otitọ fun El-Zakzaky ati iyawo rẹ atawọn ti awọn ologun pa niluu Zaria.

Image copyright @Shuleman El-zakzaky

Ọpọ ẹmi lo ti sun tawọn miiran si farapa ninu ikọlu to waye laarin awọn ọlọpaa ati ẹgbẹ Shiite.

Iléẹjọ́ gba onídùròó El-Zakzaky, ó ní kó lọ gba ìtọ́jú lókè òkun

Ìròyìn tó ń tẹ̀ wa lọ́wọ́lọ́wọ́ ní sọ pé ileẹjọ giga ilu Kaduna, ti gba oniduro olori ẹsin Shiite, Ibrahim El-Zakzaky ati iyawo rẹ.

Zakzaky ati iyawo rẹ lo ti wa ni ahamọ lati bii ọdun marun sẹyin, ti ileẹjọ ko si gba oniduro rẹ.

Bakan naa ni ile ẹjọ naa ni El Zakzaky ati aya rẹ ni anfaani bayii lati rin irin ajo lọ gba itọju ni orilẹede India, amọ awọn asoju ikọ olupẹjọ gbọdọ kọwọrin pẹlu rẹ lọ si ibi ti yoo ti gba itọju naa.

Bẹẹ ba gbagbe, awọn ọmọ ẹgbẹ Shiitee lo ti gun le iwọde alagbara eyi to la ẹmi lọ lati bii ọjọ melo kan, ti wọn si n beere fun itusilẹ asaaju wọn to wa ni ahamọ naa.

Lati idaji oni ọjọ Aje, ni awọn agbofinro ti duro wa wa wa si ẹnu ọna abawọle ile ẹjọ naa, ti wọn si n se ayẹwo awn eeyan to fẹ wọle sibẹ.