Sunday Igboho: A lè kojú Fulani táwọn ọba alayé àti àgbà Yorùbá bá tì wá lẹ́yìn

Sunday Adeyẹmọ, ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho, lasiko to n ba BBC Yoruba fọrọwerọ salaye pe, ti awọn agbaagba ati ọba alaye nilẹ Yoruba ba setan lati fi ọwọ si iwe adehun, lati ran oun ati awọn alagbara miran nilẹ Yoruba, lọ koju awọn Fulani to n da eto aabo wa ru, oun setan lati lọ.

Sunday Igboho fikun pe, lootọ ni awọn agbaagba kan nilẹ Yoruba n ri jẹ ninu eto aabo to mẹhẹ yii, amọ agba to ba setan lati fi atunbọtan rere silẹ de ọmọ, ko gbọdọ dalẹ iran Yoruba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Igboho sọ siwaju si pe ọpọ awọn eeyan to mọ iru itu ti oun pa lasiko ogun Modakẹkẹ ati Ifẹ lo maa n kan saara si oun, to fi mọ bi oun se duro ti Rashidi Ladọja lasiko to wa nipo gomina nipinlẹ Ọyọ ti wọn ko fi lee yan jẹ.

O wa fọwọ gbaya pe agbara melo ni awọn Fulani ni, ti wọn fi n da Yoruba laamu, amọ ti oun ati awọn eeyan miran ba ri atilẹyin awọn oriade nilẹ Yoruba, ti awọn si lo awọn ohun ajogunba lati ọdọ awọn baba nla wa, awọn Fulani yii ko lee duro de awọn.

Bakan naa lo fi idi rẹ mulẹ pe, ootọ ni ọrọ tawọn kan n sọ pe oun lee pasẹ fun ibọn pe ko yọ jade latinu afẹfẹ, kii si se ẹnu lasan ni.

Ọrọ pọ ti Sunday Igboho sọ ninu fidio yii pẹlu BBC Yoruba, ẹ sa wa nkan fidile lati woo.