Tope Alabi: Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni mo ti ń bá Adẹ́rùpọkọ̀ ṣe eré tíátà

Tope Alabi Image copyright Tope Alabi

Gbajugbaja akọrin ẹmi nni, Tọpẹ Alabi ti salaye pe oun ko mọ ohunkohun nipa boya awọn alawo lo sin oku adari ijọ to n lọ tẹlẹ nilu Eko, Oloogbe, Oluṣọagutan Iretiọla Ajanaku.

Lasiko to n kopa lori eto kan ni ikanni BBC Yoruba, Tọpẹ Alabi sọ pe Ọlọrun ti sọ fun oun tẹlẹ ki Ajanaku to ku pe, oun ko gbọdọ lọ si ile ijọsin rẹ mọ, bẹẹ si ni orilẹede Amẹrika ni oun wa nigba ti Ajanaku dagbere faye ati igba ti wọn sin in.

Tọpẹ salaye pe ko si ọ̀rọ̀ ikọkọ laarin oun ati ojisẹ Oluwa naa, gẹgẹ bi awọn eeyan kan ti n sọ kiri, pẹlu afikun pe ti iru eyi ba wa, Ọlọrun ni yoo se idajọ laarin awọn.

O fikun pe o to ọdun meji ti oun ko ti lọ sile ijọsin Ajanaku mọ ki ojisẹ Ọlọrun naa to jade laye pẹlu afikun pe gbogbo aye gan lo mọ pe aarin oun ati Ajanaku ko gun mọ ki onitọun to jade laye.

Tọpẹ Alabi to ni oun n kọ ile iwe kan lọwọ fun iṣẹ orin , wa gba awọn eeyan nimọran lati mase lo ẹbun ẹlẹbun, tori o dara ki onikaluku mọ ẹbun ti Ọlọrun ba fun.

Image copyright Tope Alabi

Nigba to n sọrọ lori awọn ipenija to n koju rẹ, Tọpẹ Alabi ni ọrọ alufansa ti awọn eeyan kan maa n sọ nipa awọn olorin ni kii fun awọn ni iwuri, to si laa pe oun si n kọ orin nipa ijọba ọrun, tori ko si ohunkohun to lee gba orin ijọba ọrun ni ọwọ oun.

O fikun pe ọwọ oun di pupọ ni ko jẹ ki oun maa kọ orin fun awọn elere tiata mọ bi o tilẹ jẹ pe owo ti oun maa n gba fun orin kikọ pọ lọwọ wọn, sibẹ, wọn si maa n fi orin inu ere lọ oun.

Tọpẹ ni ojoojumọ ni oun maa n gba imisi orin lati ọdọ Ọlọrun, to ba si jẹ pe bẹẹ ni oun se n se awo orin jade ni, ilẹ yoo ti kun.

Image copyright Tope Alabi

Lasiko to n sọ nipa igbe aye rẹ, ilumọọka akọrin ẹmi naa ni idile kola-kosagbe ni oun ti wa, ọmọ ọdun meje si ni oun wa, ti wọn ti sọ asọtẹlẹ fun awọn obi oun pe oun yoo sisẹ sin Ọlọrun.

O ni ọmọ ọdun mẹjọ ni oun wa ti oun fi darapọ mọ ẹgbẹ osere Adẹrupọkọ nilu Ibadan lati maa se ere tiata, ki oun to tun lọ sọdọ oloogbe Isọla Ogunsọla