CS Mum: Omotolani Ekene ní ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ọ̀lẹ, arugún, aláìlera ni ẹni tó fi abẹ bímọ

Oju abiyamọ n ri to, ko to fi inu soyun, paapa ni ọjọ ikunlẹ ati lẹyin ibimọ.

Oniruuru ẹsin, ẹlẹya ati itiju si lo maa n la kọja ko to loyun ati lẹyin to ba bimọ tan.

Bẹẹ lọrọ ri pẹlu Ọmọtọlani Ekene, ẹni to salaye iru ipo idẹyẹsi to la kọja lọwọ awọn eeyan, tori pe o fi isẹ abẹ bimọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O salaye pe, ọpọ eeyan gba pe ọlẹ, arugun, alailera ati obinrin ti ko pe ni ẹni to ba fi isẹ abẹ bimọ.

Ekene ni awọn ọrọ ẹlẹya yii dun oun de ibi pe, oun mu ọbẹ lati lọ gba ẹmi ara oun lọjọ kan.

Obinrin naa, to ti da eto kan silẹ to pe ni ‘Diary of CS Mum’ wa fi tayọtayọ sọ lẹyin o rẹyin pe, inu oun maa n dun lati wo oju apa isẹ abẹ naa, tori pe oun ri nkan ti oun se isẹ abẹ fun.