Babangida: Èròǹgbà ọmọ Nàíjíríà pọ̀ èyí tó ṣòro láti bá pàdé

Ibrahim Babangida Image copyright Twitter/Presidency
Àkọlé àwòrán Ọrọ lori orilẹede Naijiria

Olori orilẹede Naijiria tẹlẹ ri, ajagunfẹhinti Ibrahim Babangida ti ṣapejuwe Naijiria gẹgẹ bi orilẹede to ṣoro lati dari.

Babangida fọrọ yii lede lasiko tawọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu PDP kan sii nile rẹ niluu Minna, ni ipinlẹ Niger.

Babangida tun lo anfani naa lati kepe awọn aṣofin gbọdọ ṣiṣẹ takuntakun lati rii wi pe orilẹede Naijiria wa ni iṣọkan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ṣalaye pe, gbogbo ohun to n ṣẹlẹ ni Naijiria ni oun n fi ọkan ba lọ, to si gbe oṣuba kare fawọn alaṣẹ ile igbimọ aṣoju ṣofin l'Abuja, adari ile ati gbogbo ile lapapọ.

O rọ wọn wi pe, ki wọn maa kaarẹ ninu akitiyan lati ri wi pe Naijiria toro, nitori oriiṣiriiṣi erongba lawọn ọmọ Naijiria ni eyi to jẹ ko ṣoro fun awọn alaṣẹ lati dari.

Babangida fun wọn ni idaniloju pe, oun wa pẹlu wọn ninu igbesẹ wiwa ilọsiwaju fun orilẹede Naijiria.

O tun gba wọn nimọran pe, ki wọn mase gbagbe lati mu awọn ileri ti wọn ṣe fawọn to dibo yan wọn lẹkun ti wọn n ṣoju sẹ, nibayii ti wọn ti wa nile aṣofin l'Abuja.