Yollywood: Sinimá Ajé Ọjà tún so Fathia àti Saheed Balogun pọ̀

Yollywood: Sinimá Ajé Ọjà tún so Fathia àti Saheed Balogun pọ̀

Yoruba ni ọja ti ọmọ ba ti wọ, o di okuta, bẹẹ si ni ija ifẹ ko lọ titi, ki ẹlẹnu sọnu.

Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu ibasepọ tọkọtaya Saheed ati Fathia Balogun, taa gbọ pe ipinya ti de si aarin wọn tẹlẹ, amọ lẹyin ọdun mẹrinla, wọn pada joko se sinima papọ.

Lasiko ti BBC Yoruba fẹsẹ kan de si ibi ti wọn ti n ya sinima naa, a ri tọkọ-tiyawo naa ti wọn dijọ n sọrọ, abala kan tiẹ wa ninu sinima naa, ti Fathia gbe ori le Saheed lẹsẹ.

Bakan naa ni ẹni to n dari sinima Aje Ọja, Abiọdun Ọlanrewaju, ti gbogbo eeyan mọ si Abbey Lanre ni inu oun dun, nigba ti oun gbọ pe Saheed yoo ma kopa ninu sinima ti Fathia fẹ se, eyi to tumọ si pe o ti rẹ ija laarin awọn mejeeji ni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba, Fathia Balogun ni sinima Aje Ọja ti oun sẹsẹ se yii, ni yoo fi da awọn eeyan loju pe ija ti dopin, ti ogun si ti tan laarin oun ati Saheed Balogun.

Fathia fikun pe, lasiko ti ọja Yaba, nilu Eko jona ni imisi wa fun oun lati se sinima Aje ọja, nitori lasiko naa ni oun gbọ pe, bi ọja kan ba ti jona, aje kii pada sibẹ mọ.

Ẹ fun oju lounjẹ lati wo ipa ti Fathia ati Saheed Balogun ko ninu sinima Aje Ọja.