Revolution Now: NLC ní bí agbófinró ṣe mú Soworẹ àti àwọn yókù rẹ̀ sí àhámọ́ tẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú

Aṣia ẹgbẹ oṣiṣẹ Image copyright Getty Images

Ẹgbẹ oṣiṣẹ l'orilẹede Nigeria, NLC, ti keboosi pe ki wọn o tu Omoyele Sowore ati awọn oludije miran silẹ ni kiakia.

Ẹgbẹ osisẹ, ninu atẹjade kan ti Akọwe apapọ rẹ, Comrade Peter Ozo-Eson fi sita, kede pe o jẹ iyalẹnu bi awọn oṣiṣẹ alaabo "ṣe kọlu awọn to ṣe iwọde Revolution Now l'ọjọ Aje, ti wọn si mu wọn lọ si ahamọ.

NLC tọka si i pe, ẹtọ gbogbo ọmọ Naijiria ni labẹ abala ofin ikọkandinlogoji ati ogoji ninu iwe ofin Naijiria, lati ṣe iwọde ti ko ni jagidijagan, ti wọn si tun ni ẹtọ lati korajọpọ tabi darapọ mọ ipejọpọ to ba wu wọn.

O ni "Oju ti a fi wo bi awọn oṣiṣẹ alaabo ṣe kọlu awọn oluwọde alaafia ọhun, ni titẹ ẹtọ ọmọniyan loju."

"Iwọde alaafia tako iṣejọba ti ko dara tabi awọn igbesẹ ati ilana ijọba ti ko dara fun araalu, jẹ ọkan lara awọn ẹtọ ọmọniyan to ṣe koko, to si n mu ki eto iṣejọba awaarawa o dagba si.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

A ko si gbọdọ fi aaye gba awọn oṣiṣẹ alaabo wa, lati maa fi ara wọn han gẹgẹ bi ọta iṣejọba awa ara wa gẹgẹ bo ṣe han ninu iwa wọn l'ọjọ Aje."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionRevolutionNow: Ẹ̀rù ò bàwá, a ṣetan láti wà ní àtì mọ́lé- olùfẹ̀hónúhàn

Bakan naa ni Ọgbẹni Ozo-Eson tun sọ pe, bi awọn oṣiṣẹ ajọ alaabo DSS ṣe fi oludasilẹ iwọde Revolution Now, Omoyele Sowore si ahamọ, ko ba oju mu to, nitori pe igbesẹ Sowore ko fi ibi kankan dunkooko mọ iṣọkan tabi ijọba Naijiria.