Ìtàn Mánigbàgbé: Ìtàn tó rọ̀ mọ́ ìdí tí wọn ṣe ń pe aya ní ìyàwó

Iyawo tuntun

Ni aye ode oni, ede to wọpọ julọ ti awọn eeyan maa fi n pe obinrin ta ba fẹnisu-lọka, to n ba ni gbe inu ile ni 'Iyawo' eyi ti a lee sọ pe ko ri bẹẹ ni aye atijọ, tori aya ni wọn n pe obinrin ta fẹ sile, gẹgẹ bii ojulowo ede Yoruba ti kọ ni.

Koda, a lee ni ko si ohun to jọ ede ti wọn n pe ni iyawo lode oni ninu ede Yoruba, bi kii ba se isẹlẹ kan to waye lasiko kan, eyi to mu ki Iyawo wọ inu ede Yoruba, ti wọn si tun n pe awọn aya ni ọọdẹ ọkọ ni iyawo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Alaye ree lori bi 'Iyawo' se wọ inu ede Yoruba:

Ni igba iwasẹ, nigba ti oju si wa ni orunkun, ilu kan wa ti wọn n pe ni ilu Iwo lẹba ilu Osogbo, eyi to si wa titi di aye ode oni.

Aba Iwo lo bi ọmọbinrin orekelẹwa kan, to dun wo, to si jẹ oju ni gbese eyi ti wọn n pe ni Wuraọla.

Wuraọla dagba, o si di ẹni to to lọ sile ọkọ. Ọpọ ọkunrin lo n jẹ dodo ẹwa ti Ọba oke fi jinki omidan ọlọpọ ẹwa yii, to si n da gbogbo ọkunrin lọrun bii ọlẹlẹ aawẹ.

Apọnbeporẹ, ẹlẹyinju ẹgẹ, ibadi aran, idi ilẹkẹ ayilukọ ni Wuraọla, ko si si ẹni ti yoo pade omidan yii lọna, ti ko ni gbadura pe ki ori jẹ ki oun fi se aya, tori ọba oke pari isẹ si lara.

Ni aarin ilu Iwo, gbogbo ọkunrin to wa nibẹ lo n tọ Wuraọla lọ pe o wu awọn lati fi se aya, yoo si dara ko ju ọwọ silẹ fun awọn, ki awọn lee tọju rẹ.

Gẹgẹ bẹẹ se mọ pe ọmọ ọla tun ni Wuraọla yatọ si pe o tun jẹ ọlọpọ ẹwa, ọwọ ifẹ ti awọn ọkunrin si n na si omidan naa ko ni itumọ kankan sii, tori ko jẹ hoo fun ọkunrin kankan laarin wọn, to si maa n fi ọpọ wọn se akọ.

Lọpọ igba ni yoo maa yọ aleebu ara awọn ọkunrin to ba dẹnu ifẹ kọọ ni ọkọọkan lọna ati le wọn kuro ni sakani rẹ. Oun ni yoo ri ọkunrin to mukun, eyi ti oju rẹ da, eyi ti ẹnu rẹ n run ati eyi to burẹwa, ti ko si si ọkunrin kankan to tẹ Wuraọla lọrun laarin ilu Iwo.

Ni ọpọ awọn ilu okeere naa, awọn ọkunrin ko dẹyin lati maa wa beere ọwọ Wuraọla llati fi se aya. Awọn akinkanju ọkunrin, olowo, ọlọrọ ati ọkunrin to jẹ oju ni gbese lo n nawọ ifẹ si Wuraọla, ti wsn si n wa lati ilu odikeji.

Lara wọn la ti ri Ogun, Sango, Ọbatala ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti wọn n ya kẹtikẹti wa silu Iwo pẹlu erongba lati fi Wuraọla se aya, sugbọn ibinu nla ni wọn n ba kuro, ti ibanujẹ yoo si dori agba wọn kodo tori Wuraọla ko setan lati fi eyikeyi wọn se ade ori rẹ.

Yatọ si pe ọmọge yi n ja wọn kulẹ lai jẹ hoo fun wọn, se ni yoo tun maa sọ ọrọ alufansa, ọrọ kobakungbe si wọn lasiko ti wọn ba dẹnu ifẹ kọọ, eyi to mu ki gbogbo wọn tete maa ba ẹsẹ wọn sọrọ nitori wọn ko lee farada eebu to n bu wọn yii.

Ni ọjọ kan, Ọrunmila, ti oun naa jẹ arẹwa ọkunrin pinnu lati lọ silu Iwo, ko lee fi Wuraọla se aya, amọ ko to gbera kuro ni ile, lo ti kọkọ beere lọwọ Ifa atun ori ẹniti ko sunwọn se, lati beere pe bawo ni ọhun yoo ti ri.

Ifa ni ọhun yoo dara, eyiun ti ọrunmila ba ti lee se suuru pẹlu Wuraọla.

Image copyright @jenneric

Ni kete ti Ọrunmila si gunlẹ si aafin Iwo, ose, oju mimọ ati eebu ni Wuraọla fi pade rẹ, sugbọn Ọrunmila kan rẹrin musẹ lai sọ ohunkohun pada. O ki ọba Iwo bo se yẹ, to si tun mu ẹbun dani fun ọba.

Ọrunmila lo ọjọ meje ni ilu Iwo amọ Wuraọla ko fi lọrun silẹ pẹlu ọrọ abuku, to si mu kile aye le fun amọ Ọrunmila ko fesi pada, koda o tun lo ọpọn Ifa Ọrunmila lati dana.

Bi o tilẹ jẹ pe eyi bi Ọrunmila ninu amọ ko gbe soju rara,ti ko si tori rẹ sa kuro nilu Iwo.

Wuraọla kọ, ko fun Ọrunmila ni ounjẹ ati omi, sibẹ Ọrunmila ko fọhun, ti ko si binu pẹlu.

Nigba to di ọjọ keje ti Ọrunmila ti n fi ara da iya yii ni ọba Iwo fa Wuraọla fun bii aya. Ọba ni Wuraọla mọọmọ n huwa ika yii si awọn to ba dẹnu kọọ ni lọna ati mọ bi wọn se ni suuru, ifarada ati ipamọra si.

Ọba ni Ọrunmila jẹ onisuuru, alaanu, ati onifarada eniyan, ti oun ati Wuraọla si kuro lọ si ilu Ọrunmila lọjọ keje.

Nigba ti Ọrunmila de ilu rẹ, inu awọn ara ilu rẹ dun lati ri pe Wuraọla papa ja mọ Ọrunmila lọwọ, ti wọn si n beere pe nibo ni aya rẹ naa wa, awọn fẹ rii.

Ọrunmila wa nahun ke si Wuraọla pe"Iya ti mo jẹ ni Iwo", lati igba naa wa ni wọn ti n pe Wuraọla ati gbogbo obinrin to ba wọle ọkọ ni 'iyawo' tabi 'Iya-Iwo', eyi tii se agekuru "Iya ti mo jẹ ni Iwo."

Ẹkọ ti itan naa kọ wa:

O yẹ ki awọn ọkunrin maa ni ipamọra, suuru ati ifarada pẹlu aọn obinrin abi ipokipo ti a ba ba ara wa

Ko yẹ ka maa gba kamu pe ko lee see se ta ba ri ijakulẹ awọn eeyan miran lori ohun kan

Suuru ni baba iwa, o yẹ ka maa mu suuru ninu ohun gbogbo, ka lee bori nigbẹyin.