Eid-il Kabir: Iléẹjọ́ f'òfin de Oluwo pé kò gbọdọ̀ darí ìrun ní 'EID' lọ́dún Iléyá

Oba Abdulrasheed Adewale Akanbi Image copyright Facebook/Emperor Abdulrasheed Adewale Akanbi
Àkọlé àwòrán Ọrọ aṣẹ ileẹjọ

Ileẹjọ giga ipinlẹ Oṣun ti paṣẹ pe Ọba Oluwo ti ilẹ Iwo, Oba AbdulRasheed Adewale Akanbi ko gbọdọ irun Jimọh tabi ayẹyẹ ọdun Sallah ati ayẹyẹ ọdun musulumi kankan niluu Iwo.

Aṣẹ ileẹjọ naa yoo duro titi digba ti igbẹjọ lori idaduro Baṣọrun Musulumi ilẹ Iwo. Oloye Abiola Ogundokun.

Oloye Ogundokun lo rọ ileẹjọ lati paṣẹ naa fun Oluwo, o si tun pa awọn aṣoju moṣalaṣi aringbungbun ilu Iwo sọrọ naa nileẹjọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption''Ọjà ẹran àgbò kò yá bí ti ọdún tó lọ''
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSunday Igboho: Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọ̀n bàbá wa

Adajọ A.O. Ayoola ka aṣẹ naa jade lọjọ Ẹti pe Ọba AbdulRasheed Adewale Akanbi ko gbọdọ dari eto irun lọjọ Jimọh tabi nibi ayẹyẹ ọdun awọn musulumi kankan fun asiko yii.

Agbẹjọro fun Oloye Ogundokun, Opeyemi Adewale Esq. tun rọ ileẹjọ lati fofin fe Oluwo lori awọn nnkan miiran.

Ṣugbọn ilẹjọ ti sun igbẹjọ siwaju si ọjọ kọkandinlogun oṣu kẹjọ ọdun yii.

Nigba ti BBC Yoruba kan si Oluwo lori aago, Ọba Oba AbdulRasheed Akanbi kọ lati sọrọ si aṣẹ ileẹjọ.