Eid-el Kabir: Buhari rọ àwọn mùsùlùmí láti yàgò fún ìwà ipá nínú ìkíni ọdún

Aarẹ Muhammadu Buhari Image copyright Twitter/Presidency Nigeria
Àkọlé àwòrán Ọdun Ileya

Ẹ yago fun iwa ipa! Aarẹ Muhammadu Buhari ti rọ awọn musulumi Lati yago fun iwa jagijagan bi wọn ti n ṣayẹyẹ ọdun Ileya.

Buhari ni alaafia ni ki wọn maa lepa nitori ẹsin alaafia lẹsin musulumi bo tilẹ jẹ pe awọn alajagbinla kan ti fun ẹsin naa lorukọ buruku pẹlu iwa ipa wọn.

Aarẹ Buhari to sọrọ ninu atẹjade kan to fi ki awọn musulumi ki ọdun Ileya, sọ pe ifaraẹnijin to ṣe pataki julọ fawọn musulumi ododo ni pe ki wọn fi idajọ otitọ ati ododo ṣe atọna wọn lọjoojumọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption''Ọjà ẹran àgbò kò yá bí ti ọdún tó lọ''
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOro Festival: Àwọn olórò ní ọdún Màgbó ló ń gba ibi lọ, kó ire wọlé ní Ikorodu

Buhari iwa apanle ni ipenija to tobi julọ to n koju ẹsin musulumi lagbaaye bayii, aarẹ ni ọna kan gbogi lati din ipa buruku iwa yii ku ni pe koni kaluku yago fawọn waja awọn ti ko mọ wọ ti mẹ sẹ.

Bakan naa ni aarẹ Buhari rọ awọn obi lati mojuto awọn ọmọ wọn kawọn maa ba ya wọn lo lati fi wọn wuwa ipa lorukọ ẹsin.

Aarẹ Buhari dẹbi ru awọn musulumi lori ọrọ agbesunmọmi Boko Haram nitori wọn o tete dẹkun iwaasu odi tawọn Boko haram n gbe kiri ki wọn to di nla.

Buhari ko sai fi dawọn ọmọ Naijiria loju pe ijọba oun n ṣiṣẹ takuntakun lati fopin si Boko Haram, iṣẹlẹ ijinigbe ati awọn iwa ọdaran mii to gbode kan ni Naijiria.

Niluu rẹ, Daura nipinlẹ Katsina ni Aarẹ Buhari ti sọdun Ileya.