Police Killing: Iléeṣẹ́ ní àṣìta ìbọn ló pa obìnrin nílùú Eko lọ́jọ́ Satide

Awọn ọlọpaa ko gberegbe Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn ọlọpaa ko gberegbe

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko to ṣalaye aṣita ibọn lati ọwọ ọkan lara awọn ọlọpaa lo ṣekupa obinrin kan nipinlẹ naa lọjọ Abamẹta.

Tẹlẹ lọjọ Abamẹta ni fidio ọlọpaa SARS to joko silẹ ti ọpọ eeyan si rọgba yii ka lu ayelujara pa.

Ohun to tẹ le fidio niroyin taa gbọ pe ọlọpaa yii atawọn akẹgbẹ rẹ ni wọn ṣadeedee bẹrẹ si ni yinbọn nitori wọn mu ọmọ ''Yahoo'' kan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSunday Igboho: Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọ̀n bàbá wa
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOro Festival: Àwọn olórò ní ọdún Màgbó ló ń gba ibi lọ, kó ire wọlé ní Ikorodu

Nibi ti wọn ti n yinbọn ọhun lọta ibọn ti ba alaboyun kan to si paa.

Ṣugbọn atẹjade kan ti ileeṣẹ ọlọpaa fi sita yatọ si iṣẹlẹ to ṣẹlẹ yii.

Ileeṣẹ ọlọpaa ẹka to n gbogun ti awọn ajinigbe(kii ṣe SARS) lo n gbiyanju lati mu awọn afurasi ajininigbe kan lagbegbe Ijegun, lawọn afurasi ba doju ibọn ko awọn ọlọpaa.

Wọn ni nibi ti wọn jọ fija pẹta ni ọta ibọn ti lọ ba obinrin oniṣowo kan ladugbo naa.

Koda ileeṣẹ ọlọpaa ni ọga ọlọpaa kan ASP Victor Ugbegun atawọn mii farapa nibi iṣẹlẹ ọhun bẹẹ ni wọn wa nile iwosan lọwọlọwọ.

Atẹjade ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Bala Elkana fi sita ṣalaye pe Busayo Owoodun lorukọ obinrin tọta ibọn ba naa.