BB Naija 2019: Ọlọ́pàá Gẹ̀ẹ́sì bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí Khafi lórí ẹ̀sùn ṣíṣe ìbálòpọ̀

Khafi Kareem Image copyright Instagram/acupofkhafi
Àkọlé àwòrán Ẹsun ibalopọ lori BB Naija

Ọmọbinrin ọlọpaa ilẹ Gẹẹsi kan, PC Khafi Kareem ti wọ gau lẹyin to kopa ninu ere idije agbelewo ti wọn n pe ni Big Brother Naira.

Ọmọbinrin ọhun ni wọn fẹsun kan pe, o tapa sofin ile iṣẹ ọlọpaa Metropolitan Police nitori fọnran to lu ayelujara pa ṣafihan rẹ pe, o n ni ibalopọ pẹlu akẹgbẹ rẹ lori eto ọhun.

Ile iṣẹ ọlọpaa ilẹ Gẹẹsi to ṣalaye ninu atẹjade kan ti wọn fi ṣọwọ si BBC salaye pe, ọlọpaa naa beere fun aaye iyọnda lati lọ kopa ninu eto naa ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa ko fun un laaye naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa Met ni Kareem kọkọ kọwe beere fun aye lati lọ fun isinmi alaigbowo-oṣu ṣugbọn ko sọ ohun to fẹ lọ ṣe, wọn si fun laaye.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe, awọn mọ pe Kareem n kopa ninu eto agbelewo naa lọwọlọwọ lai gba iyọnda lọwọ awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa.

Àkọlé àwòrán Eto BB Naija

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ko lọwọ si bi Kareem ti wa lori eto naa ati pe, kii ṣe ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ Gẹẹsi loun n ṣoju fun niwọn igba to wa lori eto naa.

Image copyright Instagram/acupofkhafi
Àkọlé àwòrán Ẹsun ibalopọ lori BB Naija

Atẹjade ti alukoro Ileeṣẹ ọlọpaa Met, Rebecca Byng fi ṣọwọ si BBC ṣalaye pe, iwadii ti bẹrẹ lori ọrọ Kareem.

Atẹjade naa sọ siwaju si pe, o ti wa ninu ofin ati ilana ileeṣẹ ọlọpaa Met pe, wọn gbọdọ huwa bi ọmọluabi nibi kibi ti wọn ba wa.

Image copyright Instagram/acupofkhafi
Àkọlé àwòrán Eto BB Naija

Agbẹnusọ fun Khafi sọ pe Khafi yoo sọrọ si ẹsun yii nigba to ba to asiko.

Image copyright The Metropolitan Police
Àkọlé àwòrán Ẹsun ifabanilopọ lori BB Naija

Khafi jẹ aṣoju ileeṣẹ ọlọpaa Met gẹgẹ bi ọlọpaa alawọdudu nilẹ Gẹeṣi .

Ofin awọn ọlọpaa Met tun sọ pe, awọn ọlọpaa ko gbọdọ se nnkan ti yoo tabuku tabi mu ẹgbin ba orukọ ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ Gẹẹsi.

''Ọlọpaa kọlọpaa to ba tapa si awọn ilana ati ofin wọn, yoo foju wina ofin.''