Ojúde Ọba: Ayẹyẹ tó ń ṣàfihàn àṣà àjogúnbá Yorùbá

Awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ obinrin ninu asọ ẹgbẹ́jọda to n jo nibi ọdun Ojude Ọba Image copyright Ojude Oba Facebook

Ninu awọn ọdun to gbajugbaja nilẹ Ijẹbu, eyi ti tọmọde-yagba, ti onile-talejo maa n kopa ninu rẹ ni ọdun Ojude Ọba jẹ, to si tun gbajugbaja nilẹ Yoruba.

Ọjọ kẹta ọdun ileya ni ọdun Ojude Ọba maa n waye, ọdun 1892 si lo bẹrẹ lasiko ti Ọba Adesunmbọ Tunwase fun awọn musulumi nilẹ lati kọ mọsalasi si.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọdun awọn musulumi ni ọpọ eeyan ri ọdun Ojude Ọba si nigba to bẹrẹ, to si jẹ ọdun awọn ẹlẹsin kan, asiko yii si ni awọn musulumi yoo gba aafin ọba lọ lati lọ se aku ọdun sọdọ rẹ lasiko ọdun ileya, lọna ati fi ẹmi imoore wọn han fun ọwọ aanu ati ọrẹ to se fun wọn.

Image copyright Ojude Oba Facebook

Amọ kẹrẹkẹrẹ, se ni ọdun yii n fẹju si bi ọdun se n gori ọdun, to si kọja ọdun ẹlẹsin kan, lojumọ toni yii, ọdun Ojude Ọba ti di aayo nilẹ Ijẹbu, eyi ti oniruuru ẹlẹsinjẹsin, ẹlẹyamẹya, tọmọde tagba n peju lati se ajọyọ rẹ, koda, awọn eeyan, paapa awọn ọmọbibi ilu Ijẹbu maa n ti ẹyin odi wa se ayẹyẹ naa.

Lasiko ọdun Ojude Ọba, faaji maa n pin silẹ Ijẹbu ni, ti awọn Ijẹbu kii si fi ọdun Ileya sere boya ẹlẹsin Kristiẹni ni, Musulumi abi abọrisa, ti wọn yoo si wọ asọ ẹgbẹjọda lọkan o jọkan, ti gbogbo ilu yoo si maa gba yin-in lasiko ọdun Ojude Ọba.

Image copyright Ojude Oba Facebook

Awọn ohun to yẹ kẹ mọ nipa ọdun Ojude Ọba:

Afihan aṣa adayeba ati ajogunba wa lọna to yaayi:

Afojusun ọdun Ojude Ọba ni lati se amugbooro awọn aṣa, ajogunba wa ati awọn ise adayeba ọmọ ṣa, ajogunba wa ati awọn ise adayeba ọmọ Yoruba. Eyi si maa n fi oju han pẹlu ọpọ ati oniruuru asọ ẹgbẹjọda ti ẹlẹgbẹjẹgbẹ maa n wọ lasiko ọdun Ojude Ọba. Se ni asọ maa n pe asọ ransẹ lasiko ayẹyẹ naa, ti awọn ọkunrin yoo si ko si oniruuru sitaili agbada, tawọn obinrin naa yoo si lo asọ lọ bii rẹrẹ, asọ oke yoo maa pe asọ oke ransẹ ni, to fi mọ adirẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oniruuru irun didi, asọ ibilẹ, ounjẹ ilẹ Ijẹbu tii se Ifọkọrẹ ati ijo ibilẹ ko si ni gbẹyin.

Image copyright Ojude Oba Facebook

Idije ẹsin gigun, ibọn yinyin ati ijo jijo:

Lara awọn ayẹyẹ to n mu ki ọdun Ojude Ọba jẹ manigbagbe nilẹ Ijẹbu ati nilẹ Yoruba lapapọ ni bi wọn trun se n se afihan ara asa wa lọna miran, eyi to nii se pẹlu ibọn yinyin, gigun ẹsin bii ọlọla ati sise idije ijo jijo laarin awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ lsna ti mọ ẹgbẹ to gbegba oroke.

Awọn idile to n gun ẹsin yoo maa le ara wọn lare ni, ti wọn yoo si wọ oniruuru asọ ti wọn fi n se idije ẹsin gigun laarin awọn ọkunrin, tawọn obvinrin naa yoo si maa tadi reke lati pa ara wọn layo lasiko ọdun Ojude Ọba.

Awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ti wọn n pe ni Rẹgbẹrẹgbẹ to wa ni isọri-isọri ọjọ ori kọọkan ni yoo se afihan bi wọn se lee tadireke si. Ẹgbẹ to ba si gbegba oroke ni wọn yoo fun ni ẹbun to jọju lasiko ọdun Ojude Ọba, ninu eyi ti wọn yoo maa yin ibọn soke loore koore.

Image copyright Ojude Oba Facebook

Aṣa sise Kade pẹ lori, ki bata pẹ lẹsẹ fun ọba:

Lara awọn ohun pataki ti kii gbẹyin lasiko ọdun Ojude Ọba ni asa lilọ ki ọba pe ki ade pẹ lori, ki bata pẹ lẹsẹ, ki ẹsin ọba si jẹ oko pẹ. Pẹlu orin, ijo, ilu ati ayọ ọkan si ni awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ lọkanojọkan fi maa n lọ ki ọba naa to wa nikalẹ, lati igba ti ọdun Ojude Ọba si ti bẹrẹ lati bii ọgọrun ọdun sẹyin ni asa yii ko ti parun.

Koda, wọn yoo tun mu ẹbun eroja ounjẹ lọwọ fun ọba gẹgẹ bii ẹbun ọdun.

Image copyright Ojude Oba Facebook

Ọdun Ẹsin ni Ojude Ọba fi bẹrẹ:

Awọn ẹtahoro musulumi kan lo bẹrk ọdun Ojude Ọba, ko to di pe o di itẹwọgba nilẹ Ijẹbu. Sugbọn lasiko yii, ọdun Ojude Ọba ti tayọ ẹsin kan soso, ti awọn oniruuru ẹlẹsin si ti n tẹwọgba ọdun naa nilẹ yii ati lẹyin odi.

Ọjọ kẹta Ileya ni ọdun Ojude Ọba maa n waye:

Ni ọjọ kẹta ọdun Ileya ni awọn ọmọ bibi ilẹ Ijẹbu yoo korajọ pọ lati se ayẹyẹ ọdun Ojude Ọba pẹlu awọn ọrẹ, ẹbi ara ati ibatan wọn. Wọn si fi ayẹyẹ naa si ọjọ kẹta ọdun Ileya lọna ati fun awọn musulumi ni aaye ati anfaani lati gbadun ọdun Ileya ni ọjọ meji akọkọ.

Ni ọjọ kẹta yii ni awọn tọkunrin-tobinrin, ọmọde ati agba nilẹ yii ati lati oke okun yoo pe biba si gbagede kan lati se ọdun naa nilu Ijẹbu-Ode.

Image copyright Ojude Oba Facebook

Bi ọdun Ojude Ọba si se n fẹju si, to si n di itẹwọgba, naa ni aayan n lọ lati jẹ ko di ilumọọka jakejado agbaye.