Kenyan Dance Party: Òde ijó yìí kò sí fáwọn abo tó ń fẹ́ ara wọn pẹ̀lú

Awọn obinrin to n jo Image copyright The nest collective

Ti a ba n se ayẹyẹ, tọkunrin tobinrin lo maa n peju pesẹ lati fi ara kinra, eyi ti yoo mu ki ayẹyẹ naa dun, ko si larinrin.

Sugbọn iyalẹnu gbaa lo jẹ lati ri pe ode ijo kan lee wa, ti yoo wa fun kikida awọn obinrin nikan, ti wọn yoo si le awọn akọ sẹyin.

Gẹgẹ bi BBC se se awari rẹ, ilu Nairobi lorilẹede Kenya ni idan orita naa ti n waye, nibiti wọn ti haya ibudo kan to wa fun ile ijo, ti orin si n dun lakọlakọ nibẹ, sugbọn kinni kan to ba Ajao jẹ, ti apa rẹ fi gun ju itan lọ ni pe kikida awọn obinrin lo wa lagbo ijo naa, to n jo pẹlu ara wọn.

Gẹgẹ bi awọn obinrin to ba BBC sọrọ ti wi, o dara ni ẹkọọkan bayii lati maa fi ọwọ lile mu awọn ọkunrin, ti awọn obinrin nikan yoo ti da wa laisi awọn ọkunrin nibẹ.

Jane, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, lasiko to n ba BBC sọrọ ni, "ọkan mi balẹ lati wa si agbo ijo to wa fun obinrin nikan lai lọwọ awọn ọkunrin ninu, mo wa pẹlu ọrẹ mi obinrin, eyi to mu ki inu mi dun lati wa pẹlu ẹni to loye nipa oun."

Nibi agbo ijo naa, se ni ipese abbo to peye wa, iwọnba awọn ọkunrin ti wọn si gba laaye lo wa ja awọn obinrin silẹ, ni kete ti wọn ba si se bẹẹ tan ni wọn yoo jade kuro nibẹ.

Koda, awọn eeyan to jẹ agbọti, agbounjẹ, osisẹ eleto aabo, awọn gbogbo elere to n lu awo orin, awọn atọkun eto to fi mọ awọn asọna lo jẹ obinrin, laisi ọkunrin ninu wọn.

Ọdun 2018 ni wọn bẹrẹ agbo ijo awọn obinrin nikan naa, ti erongba idasilẹ rẹ si kọja jijẹ igbadun alẹ ọjọ kan. Idi ni pe oju awọn obinrin ri mabo lọdun to kọja naa nitori awọn isẹlẹ hihu iwa ipa si awọn obinrin ati ifipabanilopọ, eyi to mu ki awọn obinrin pinnu lati maa da wa laisi ọkunrin.

Yatọ si eyi, agbo ijo aọn obinrin naa ko si fun awọn abo to n fẹ ara wọn, taa mọ si Lesbian, ti ode naa ko si wa fun ẹlẹsin kan pato.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC, Munira, ẹni ọdun mejilelogun ati Khadija, ẹni ọdun mẹẹdọgbọn, ti wọn jẹ mususlumi salaye pe ode ijo naa ba ilana ẹsin Islam mu, eyi to faramọ ki awọn ọkunrin maa da wa loju kan.

"Ọpọ wa lo maa n bọ asọ ibori (Hijab) wa lati darapọ mọ awọn akẹẹgbẹ wa lasiko ta ba n jo. Idi ni pe ti wọn ba ri wa pẹlu Hijab, wọn yoo ya ẹnu pe ki la wa se nibẹ."

Iru ipejọpọ bayii ni Munira lo dara pupọ nitori wọn ko fi aaye gba awọn lati maa fara ro ọkunrin.

Ireti si wa pe laipẹ laijinna, irufẹ ode ijo bayii yoo tan kalẹ bii ọwara ojo yika gbogbo ilẹ Afirika, nibiti wọn yoo ti maa gbe awọn obinrin larugẹ bo se yẹ.