2023 Presidency: Àwọn ọmọ Nàìjíríà ń dá awuyewuye sílẹ̀ lórí Tinubu ní Twitter

Bola Ahmed Tinubu Image copyright @AsiwajuTinubu

Tinubu, Tinubu, Bọla Ahmed Tinubu!!!, ko si ẹni ti ko mọ gbajugbaja oloṣelu yii yika orilẹede Naijiria.

Bi ọpọ ti mọọ si ogbontagi oloṣelu, lawọn miran mọọ si aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC. Jagaban ti ilu Borgu lawọn miran fi n gbe ọkọ Olurẹmi larugẹ.

Ṣugbọn ni ẹnu lọwọlọwọ yii, ohun to n gbe Bọla Tinubu si oju aje ayelujara naa ni ariyanjiyan lori bi awọn kan ṣe ṣalaye pe, o n gbero lati du ipo aarẹ orilẹede Naijiria ni ọdun 2023.

Aṣiwaju Tinubu ko tii kede boya ootọ wa ni ọrọ yii abi bẹẹ kọ, bakan naa ni ko wi fun araye pe oun ko gbaa lero.

Nibayii awọn ọmọ orilẹede Naijiria kan ti n ta ohun si ara wọn lori ikanni ayelujara Twitter, lori boya o tọna ki Tinubu du ipo aarẹ ni ọdun 2023 tabi ko tọna.

Image copyright @AsiwajuTinubu

Ohun ti awọn ọmọ Naijiria kan to n fọwọsi Tinubu fun ipo aarẹ lọdun 2023 n sọ, loju opo Twitter ni pe, ati ranmu gangan idagbasoke to de ba ipinlẹ Eko lẹnu ọdun melo kan sẹyin, ko ṣẹyin eekan Tinubu.

Wọn ni eyi ko sẹyin ilana ti Bọla Tinubu fi lelẹ, lasiko to jẹ gomina ni ọdun 1999 si ọdun 2007, eyi ti wọn ni ọpọ awọn gomina si n tẹle.

Wọn ni bi Tinubu ba di aarẹ, o lee tun gbe ọwọ to lo ni ipinlẹ Eko lọ si ijọba apapọ, fun idagbasoke orilẹede Naijiria lapapọ.

Amọṣa, awọn eeyan miran n ṣalaye lori ẹrọ ayelujara pe ni iwoye tiwọn, Tinubu wa lara awọn iṣoro orilẹede Naijiria.

Wọn ni Tinubu wa lara awọn to mu ki ọpọ dibo fun aarẹ Buhari ni ọdun 2015 ati ni ọdun 2019.