Seyi Makinde: Gbogbo ẹ̀yin tí ipò kò tíì kàn, ẹ fọkàn balẹ̀, yóò kàn yín láìpẹ́

Seyi Makinde Gomina ipinle Oyo Image copyright Facebook/Seyi Makinde

Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo Seyi Makinde ní àwọn agbáṣésẹ abẹ́lé ní ìjọba òun yóò maa gbé kọ́ngila ìpínlẹ̀ Oyo fún, lójunà àti kó ipa tiwọn nínú ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ náà.

Makinde fọ̀rọ̀ yìí léde làsìkò to ń bá àwọn eeyan ilu Ogbomosọ sọrọ nígbà tó lọ sàbẹ̀wò "ẹ ṣeun, mo dupẹ" si wọ́n ní ìlú náà, fun atilẹyin ti wọn se fun lasiko eto idibo gomina to kọja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ní àwọn kọgila tó dáńtọ́ tí wọ́n sì mọ iṣẹ́ wọ́n bi iṣẹ́ tí akọsílẹ̀ sì ti fi hàn pé wọ́n kìí fi iṣẹ́ wọ́n ṣere ni àwọn yóò kọ́kọ́ gbé iṣẹ́ fún ní kété ti ìjọba bá ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òde.

Gómìnà ní ìjọba ò ti gbé iṣẹ́ kankan jáde láti ìgbà ti o ti dé, àti pé kí àwọn ara ilú lọ mú ọkàn wọ́n kúrò nibi pé bóya àwọn ti gbé iṣẹ́ fún àwọn ará ìta

Image copyright SeyiMakinde
Àkọlé àwòrán Seyi Makinde, lásìkò tó ń dúpk lọ́wọ́ àwọn Ogbomoṣọ

Dípò bẹ́ẹ̀ "a ó gbé iṣẹ́ fún kọngilá tó jẹ ará ìlú láti mú ìdàgbàsókè bá ètò ọ̀rọ̀ ajé ìpiínlẹ̀ Oyo àti láti jẹ́ kí wọ́n ni ipa nínú ìjọba"

O rọ gbogbo àwọn ti wọ́n ń retí ìpò kàn tàbí òmíràn nínú ìjọba rẹ̀ láti lọ fí ọkàn balẹ̀ nítorií yóò kàn wọ́n láìpẹ́.

Bakan naa lo tun rọ awọn awọn araalu pe eto idẹrun wọn lo mumu julọ ni aya ijọba oun, ti oun yoo si tukọ ipinlẹ Ọyọ pẹlu ibẹru Ọlọrun.