DFL: Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí tún ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ girama ní iṣẹ́ Asoná, bàtà àti báágì ṣíṣe

Atẹlẹwọ ẹni kii tan ni jẹ ni Yoruba n sọ, idi ree ti ajọ kan ti wọn n pe ni Design For Life (DFL) se gunle eto idanilẹkọ fawọn obinrin to wa nile ẹkọ girama, lati kọ awọn isẹ miran to n mu owo wale yatọ si isẹ aransọ.

Lara awọn isẹ ti DFL n kọ wọn ni isẹ lilo ankara lati fi se bata ati baagi, isẹ kafinta, eyi to jẹ pe awọn obinrin kii saba ya sidi rẹ ati isẹ aso ina taa mọ si Electrician.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n sọrọ pẹlu BBC, Oludari ajọ naa Ọmọwe Bukọla Aluko Kpotie salaye pe, awọn isẹ ti awọn obinrin pa ti fun awọn ọkunrin yii lo ni owo lori, ti oun si gba lati maa kọ awọn akẹkọọ lati ile ẹkọ girama lọna ti wọn fi lee mọ awọn isẹ wọnyii.

Bakan naa lo gba pe, ko si ohun ti awọn ọkunrin n se, ti awọn obinrin ko lee se ju bẹẹ lọ, idi si ree ti awọn obinrin fi yẹ ko kọ awọn isẹ miran tawọn ọkunrin n se, lọna ati maa pawo wọle, yatọ si isẹ aransọ.

Produced b: Yemisi Oyedepo ati Bayo Odukoya