PDP South West: Ọ̀rọ̀ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ìjọba tó pòórá kìí ṣe ìṣẹ̀lẹ̀ àfojúfò

Asia ẹgbẹ oselu PDP Image copyright @OfficialPDPNig

Ẹgbẹ oselu PDP lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria ti faraya lori gbolohun kan ti gomina ana nipinlẹ Ọyọ, Abiọla Ajimọbi sọ pe, ọrọ ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn lo poora jẹ isẹlẹ kekere ti ko lowura rara.

Idi si niyi ti ẹgbẹ oselu PDP naa fi n nahun kesi gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde pe ni kia mọsa, ko yara tete tanna wadi bi ijọba Ajimọbi se lọ, ki awọn ohun ikọkọ lee foju han ni gbangba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Atẹjade kan ti ẹgbẹ oselu PDP lẹkun iwọ oorun Guusu Naijiria fisita, eyi ti akọwe ẹgbẹ lẹkun naa, Ayọ Fadaka fọwọsi lo sisọ loju ọrọ yii, lasiko to n fesi si ọrọ kan ti Abiọla Ajimọbi sọ pe iti ọgẹdk lasan ni awọn ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn lo sọnu, ko to ohun ti a n yọ ada si.

Image copyright @AAAjimobi

PDP sọ siwaju si pe igbesẹ sise ayẹwo isejọba to kọja yoo fun ijsba tuntun to wa nipinlẹ Ọyọ ni anfaani lati mọ ọpọ igbesẹ ti ijọba Ajimọbi gbe lori aleefa.

Atẹjade naa salaye pe "Ijọba ipinlẹ Ọyọ lo n gbọ bukata lori awọn ọkọ ayọkẹlẹ ti ijọba Ajimọbi ra lati osu keji ọdun 2019, amọ ti awọn ọkọ naa ti di awati bayii, irufẹ awọn ọkọ tuntun yii si ni a ko lee sọ pe wọn ko se lo mọ."

Ẹgbẹ oselu PDP wa n kesi Ajimsbi pe ko maa ranti atubọtan, ati itan ti ọjọ ọla yoo sọ nipa rẹ ati isejọba rẹ, ti wọn si n rọọ lati kesi awọn eeyan to yan sipo pe ki wọn tete da awọn ọkọ ayọkẹlẹ naa pada.