Ojude Oba 2019: Ọba Adetọna ní bí òun bá papòdà, ẹni tó bá dáńtọ́ ni kí wọ́n fi jẹ Awùjalẹ̀

Ọba Adetọna L'Ojude ọba 2019

Ṣe awọn agba bọ wọn ni, bi ẹyin agba yoo ṣe ri, oju rẹ laa tii mọ.

Eyi lo difa fun awujale ilẹ Ijẹbu Ọba Sikiru Adetọna, to fi fa awọn eeyan rẹ leti pe, a lee pe yoo pẹ ko ya, a si le pe yoo ya ko pẹ.

Amọṣa o ni kete ti oun ba ti darapọ mọ awọn alalẹ, "ẹni to ba dantọ ni ki wọn yan si ipo naa" lẹyin oun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lasiko ọdun ojude ọba to waye nilu Ijẹbu Ode lọjọ iṣẹgun, ni Awujalẹ ti gbe sọrọ nla yii fun awọn eeyan rẹ, paapaa julọ awọn afọbajẹ.

O ni ki wọn ta kete sawọn owo-o-magọ ati olowo igbo tii n ṣilẹ f'ole, ti wọn lee fẹ fi owo ra apere ọba ilu naa nitori pe, gẹgẹ bi Ọbalaye naa ṣe sọ, ifasẹyin ni iru wọn maa n fa ba ilu.

Ọdun 1960 tii ṣe aadọta ọdun sẹyin, ni Ọba Sikiru Adetọna gun ori itẹ; ọmọ ọdun marundinlọgbọn si ni nigba naa, to gun ori itẹ.

Àkọlé àwòrán Awujalẹ ilẹ Ijẹbu, Ọba Sikiru Adetọna ni nibi ti ọrọ idagbasoke ilẹ Ijẹbu de duro bayii, ọlanrewaju lo yẹ ki ẹni ti wọn yoo fi jẹ Ọba nibẹ o jẹ

Ohun ti ọpọ n bi ara wọn leere bayii ni pe, abi baba ti n gbaradi silẹ fun didarapọ mọ awọn alalẹ ilẹ naa ni? Ṣe wọn ni iku o dọjọ, arun o doṣu.

Ọba Adetọna ṣalaye siwaju pe, inu oun dun de ibadi lati ri awọn igbesẹ idagbasoke ati ilọsiwaju to ti de ba ilẹ Ijẹbu.

O ni awọn ọmọ ilẹ naa gbọdọ ja fitafita lati maa tẹ siwaju lori rẹ nipa riri daju pe wọn ko fi aye silẹ fun awọn kan lati fi owo ra ipo Ọbalaye ilẹ naa.

"Nigba ti asiko ba to ti mo ba lọ, mo bẹ yin, ẹni ti o to gbangba sun lọyẹ ni ki ẹ yan sipo. Ẹ kọ ipakọ si ẹnikẹni ti yoo fa ọwọ agogo ilẹ Ijẹbu si ẹyin.

Ẹ ma ṣe ti oṣelu bọ eto yiyan ẹni ti yoo gba ade lẹyin mi. Ẹ ma ṣe yan awọn ti yoo fa ọwọ Ijẹbu sẹyin."

O ni bi idile ti oye kan ko ba ri ọmọ oye to dantọ fa kalẹ, n ṣe ni ki awọn araalu kọ amulumala ọmọ oye ti wọn ba fa silẹ, ki wọn si mu ninu ọmọ oye ni idile to ba kan.