Ìjàmbá Eko: Èèyàn méjì dàwátì lásìkò ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi

Awọn oṣiṣẹ LASWA ni oju agbami kan Image copyright @TalktoLaswa
Àkọlé àwòrán Eyi ni igba keji ti iṣẹlẹ ijamba oju omi yoo maa waye laarin oṣu keje si ikẹjọ ọdun 2019

Ajọ irinna oju omi nipinlẹ Eko, LASWA ti kede pe, ijamba ọkọ oju omi kan ti ran eeyan mẹta lọ sọrun ti wọn si tun n wa awọn meji miran lagbegbe ileto Irewe ni Ọjọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu atẹjade kan ti Giwa ajọ LASWA, Emmanuel Oluwadamilọla fi sita, eeyan mẹtala ni wọn yọ laaye ninu ijamba naa to waye alẹ ọjọ iṣẹgun.

O ni awọn ọkọ oju omi akero meji kọlu ara wọn lagbegbe ijọba ibilẹ Ojo.

Ero mẹwa lo wa ninu ọkan lara awọn ọkọ oju omi naa, to nbọ lati agbegbe Ọjọ jetty, mẹjọ si wa ninu eyi to n bọ lati ileto Irewe, eyi to mu ki apapọ awọn ero to wa ninu awọn ọkọ oju omi naa, lasiko ti ijamba naa fi waye jẹ mejidinlogun.

"Eeyan mẹtala lo wa laaye, eeyan mẹta ku, agbalagba kan ati majesin kan ni wọn n wa bayii.